ỌLỌRUN FỌWỌ SI OLE JIJA - ỌLỌPAA TO N GBA RIBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 2, 2019

ỌLỌRUN FỌWỌ SI OLE JIJA - ỌLỌPAA TO N GBA RIBA

Fọnran fidio kan to jẹyọ lori ẹrọ ayelujara Twitter ti n da igboru ru lori bi ọlọpaa kan ti ṣe sọ ninu rẹ pe ''Ọlọrun ko lodi si ole jija.''

Ọmọ orilẹede Naijiria kan, Kayode Ogundamisi lo fi fọnran fidio naa si oju opo Twitter rẹ .

Kedere la ri arakunrin kan to wọ aṣọ ọlọpaa ti o fẹ gba owo ti a fura si pe o jẹ abẹtẹlẹ lọwọ awakọ kan ti a ko ri oju rẹ.

Awọn ọlọpaa miran wa ninu aworan naa to mu wa ro wi pe ibi ti wọn ti n da ọkọ duro fun ayẹwo,''Checkpoint'' ni iṣẹlẹ naa ti waye.

O jọ bi ẹni pe awakọ naa ko fẹ fun ọlọpaa naa ni owo to ju ẹgbẹrun kan Naira lọ ti o si mu ki ọlọpaa naa pasamọ pe ''Ki wọn ma ji mọto gbe, ki wọn ma jale, Olorun gaan faramọ ''

Ọpọ Naijiria lo lodi si ohun ti ọlọpaa naa sọ lori ẹrọ ayelujara, ti wọn si n kesi ijọba lati ṣe atunto ileeṣẹ ọlọpaa.

Arakunrin kan ti orukọ rẹ lori Twitter n jẹ @RaySensualCalls ni ko si ofin l'orileede Naijiria ati pe ọrọ to wa nilẹ yi dabi ọrọ Yoruba to sọ pe amúkùn ún, ẹru rẹ wọ, to ni oke lẹ n wo, ẹ ko wo isalẹ.

Mi o ti ri fọnran fidio naa
Iru iṣẹlẹ bayi kii ṣe ajoji pẹlu awọn ọlọpaa l'orileede Naijiria to si mu ki ọpọ eeyan ma ni ireti ninu wọn.

Alukoro ilẹeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba nigba ti ikọ BBC Yoruba ba sọrọ ni ''oun ko ti ri fọnran fidio naa'' tori eyi ''ohun ko le fesi si''

-  BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI