Gbogbo awọn
ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ni ko le tete gbagbe iya ajẹkudorogbo
ti ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool gbe le wọn lọwọ lalẹ oni ni papa iṣere
Anfield.
Idije yi lo fun ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lanfaani lati kopa ninu aṣekagba idije Champions League pẹlu bi wọn ṣe
doju Barcelona bolẹ pẹlu aami ayo mẹrin si oodo.
Goolu mẹta ni Barcelona fi n
lewaju lati abala kini ifẹsẹwọnsẹ wọn lọsẹ to kọja amọ Liverpool da goolu na
pada ti wọn si tẹsiwaju lati bori Barcelona pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta.
Divock Origi lo kọkọ jẹ goolu
ni iṣẹju keje ifẹsẹwọnsẹ naa ti o si fi goolu mi da Barcelona loro ni iṣẹju
kọkandinlogọrin ti o fi jẹ goolu mẹrin si odo.
Bi ala ni ọrọ naa ri loju ọpọ
alatilẹyin ẹgbẹ Liverpool nitori pe awọn to jẹ eekan ẹgbẹ wọn meji Mohammed
Salah ati Firminho ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Amọ aisini ori papa wọn ko fi
Liverpool rara.
Ninu idije Champions League, iru
itu bayi ṣọwọn ti awọn eeyan ṣi n kan sara si Liverpool.
Tottenham ati Ajax ni yoo koju
ninu ifẹsẹwọnsẹ keji lati mọ ẹni ti yoo pade Liverpool ninu aṣekagba idije naa
ti yoo waye ni Madrid.
No comments:
Post a Comment