Góòlù kan ní abala kíni ati meji ni abala keji ni
won fi pá enu Liverpool mọ tí o sí jọ bí ẹni pé kikopa nínú asekagba ko ní yẹ
fún wọ.
Ní sáà àkọ́kọ́ láàrin iṣẹju péréte ni Suarez ṣe gbá
bọọlu sáwọn ilé Liverpool, Sùgbọ́n Lionel Messi ko sàànú ẹni kankan nígbà to ju
góòlù èèkeji àti ẹkẹta sáwọn Liverpool.
Sùgbọ́n ni gba to di sáà keji, gbogbo ìgbìyànju
Liverpool pàbó lo jási, se ti eni ti bọọlu wà ni ìkáwọ rẹ̀ jùlọ ni ka sọ ni
tàbí ní ti gbigba bọọlu sile, ǹkan to ṣeni láànu jùlọ ni pé èyi ko ṣe pàtàki
bii ki a wọn gbà bọọlu sáwọn.
Aṣẹ̀yinwá àṣẹyin bọ, bi Liverpool ṣe lọ maa lo ṣe
bọ.
Igbìyànju Barcelona wá tún di ọbẹ fún wọn ti wọn si
ṣe bẹ ṣe ìrìbọmi mẹ́tà lọkan fún wọn àmi àyo mẹta sodo gbáko.
O dàbi pé ìdániloju to pọju fún Liverpool ninu
ifẹsẹwọnsẹ yìí lo fa ìdí ti wọn fi fidi rẹmi pátápata.
Bó tilẹ̀ jẹ pe báku à ó jẹ ẹran to ju eerin lọ, oore
ofẹ si wa pé àwọn mejeeji yóò tun pada foju rinju.
Pẹ̀lú bi ǹkan ṣe ri yìí, iṣẹ́ nla lorin kewu lo wa
niwaju Liverpool ninu abala Keji to yóò wáye ni Anifield.
Igba akọkọ
rèé ti Liverpool yóò fìdírẹmi pẹ̀lú àmi ayo mẹ́ta nínú ìdíje Champions League
ọdun yìí.
- BBC
No comments:
Post a Comment