Inu ibanujẹ ọkan lawọn mọlẹbi
ọdọmọkunrin akẹkọọ ile ẹkọ fasiti Oduduwa to wa nipinlẹ Ọṣun wa dasiko ti a kọ
iroyin yi tan, latari bo ṣe gan mọ ina lọjọ Wẹside ijẹta.
Aṣhante lorukọ akẹkọọ naa, ti
wọn si nipele keji (200L) lo wa ko too kagbako iku naa ni Ipetumọdu.
AWIKONKO gbọ pe fooni ni wọn
Aṣhante n gba ina si lọwọ lalẹ ọjọ Wẹside naa, paapaa ti wọn tun sọ pe asiko ti
ojo n rọ lọwọ ni.
Wọn ẹrọ to n gba ina sara
(transformer) la gbọ pe o gba ina lojiji, to si jẹ pe asiko naa ni Ashante fi
waya sinu ina, lojiji ni wọn sọ pe ina gbe oun naa.
Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn pada
wa gbe oku e kuro lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment