Ko sẹni to gbọ bi yaale ile
kan, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), Nneka Donatus ṣe sọrọ lọgba SARS laipẹ yi,
lori bo ṣe ta ọmọ oojọ to ṣẹṣẹ bi, to si loun ti fowo naa ra foonu, aṣọ ati
bata ti ko ni i gbe e ṣepe.
Bo tilẹ pe ọwọ ti tẹ Nneka
atawọn to ta ọmọ naa fun lẹgbẹrun lọna ẹgbata (600,000), sibẹ oun tọpọ awọn to
gbọ sọrọ naa n sọ ni pe ki wọn jẹ ki Nneka to ti bimọ marun tẹlẹ jiya ẹṣẹ ẹ,
nitori pe ọdaju abiyamọ ni.
Si iyalẹnu, ọkan lara awọn oṣiṣẹ
ijọba nipinlẹ Imo, Arabinrin Ujunwa Udechukwu, ẹni ogoji ọdun ati Nneoma Onwusereaka
ni wọn ni Nneka ta ọmọ naa fun.
Nigba to n sọrọ, Nneka sọ pe
oun ko dee de ta ọmọ naa, bi ko ṣe pe aile rowo tọju ẹ lo jẹ koun ta a, ati pe
oun ti na ninu owo naa lati fi ra foonu, bata ati aṣọ, toun tun si fi ninu ẹ wọ
mọto.
Ọdaju abiyamọ naa tun fi ye
awọn ọlọpaa pe aṣiṣe ni oyun naa jẹ, nitori pe ọmọ marun loun ti bi tẹlẹ fun
ọkọ oun tawọn ko jọ gbe papọ mọ, to si jẹ pe oun nikan loun n da bukata gbe,
idi ni yii toun fi gbe igbesẹ naa.
No comments:
Post a Comment