Idaamu nla lo de bawọn akẹkọọ ileewe Fasiti FUNAAB pẹlu bawọn alaṣẹ ati adari ileewe naa ṣe gbe ofin tuntun kalẹ pe akẹkọọ to ba wọ aṣọ iwọkuwọ lọgba ileewe naa yoo ri pipọn oju ofin.
Nigba to n gba ẹnu ọga agba to n ri sọrọ awọn akẹkọọ, iyẹn Dean of
Student Affairs, Ọjọgbọn Babatunde Idowu sọrọ ninu atẹjade to fi ranṣẹ kaakiri sawọn tọrọ kan laipẹ lo ti banujẹ lori iru aṣọ adojutini tawọn akẹkọọ naa n wọ.
O ni akẹkọọ tọwọ ba tẹ fun aṣọ iwọkuwọ naa, eyi to tako ofin imura nileewe naa yoo foju wina ofin, nitori pe awọn ko nii gba iwa ti ko yẹ ọmọluabi laaye nileewe naa.
AWIKONKO gbọ pe pupọ awọn akẹkọọ ti wọn kundun lati maa wọ awọn aṣọ ti ba oju mu naa ni wọn ti bẹrẹ si i ya owo lati ra aṣọ tuntun min in to ba ofin mu, ki wọn ma baa gba idajọ.
No comments:
Post a Comment