NITORI IPO ỌBA AGURA, WAHALA BẸ SILẸ LAAFIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 4, 2019

NITORI IPO ỌBA AGURA, WAHALA BẸ SILẸ LAAFIN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọ, ọrọ naa ti di ara ko rokun, ara ko ro adiyẹ lori ipo Ọba Agura tiluu Gbagura ti wọn lawọn kan n du lọwọlọwọ bayii.

Bo tilẹ jẹ pe o ti le loṣu mẹfa bayii ti wahala naa ti n ṣẹlẹ, ṣugbọn ohun ta a gbọ laipẹ yi ni pe ṣe ni ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ademọla Bakre n gbiyanju lati fa eeyan kan ṣoṣo kalẹ fun ilu Gbagura, ẹni naa ti wọn si lawọn araalu lawọn ko fẹ

AWIKONKO gbọ pe awọn ti ko din ni mẹtala ni wọn n du ipo naa lọwọlọwọ latigba ti Ọba Halidu Ọlaloko ti waja loṣu keje ọdun to kọja.

Diẹ lara awọn ti wọn n du ipo naa ni: Ọmọba Taofeek Adebayọ Ajani ti idile Jamolu; Saburi Ayinde Adeyẹmi ti idile Ijaade; Adebayọ Falilu Adeọṣun ti idile Adeọṣun; Ọmọba Akinyẹle Ṣarafadeen Ogunwọọlu ti idile Ijaade; Ọmọba Sabure Babajide Bakre ti idile Jamolu; Ọmọba Sufian ọlatunji Ademolu ti idile Ṣoẹtan atawọn min in.

Gẹgẹ bi aṣiri to tu s'AWIKONKO lọwọ laipẹ yi, wọn ni Ọmọba Sabure Babajide Bakre ni Ademọla Bakre to jẹ olori ẹbi Egiri fẹẹ lo lati di Ọba Agura latari pe o jẹ ọmọ ẹgbọn ẹ, ti wọn si ni lawọn araalu atawọn ti wọn jọ n du ipoko faramọ ọn.

Ohun ta a gbọ ni pe latigba ti Ọba Ọlaloko ti waja ni wọn ti yan igbimọ ẹlẹni mejila lati ṣakoso eto yiyan ọba min in, ti wọn si ni ṣe Ademọla Bakre ko faaye silẹ fawọn igbimọ naa lati ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ.

Igbimọ ẹlẹni mejila yi la gbọ pe wọn ṣepade lọjọ Tọside, ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu to kọja yi nile mọlẹbi Egiri to wa ni Oke-Ido, Gbagura niluu Abẹokuta, ipade naa la gbọ pe o da lori Ademọla Bakre, to fẹyinti gẹgẹ bi adajọ.

Wọn ni gbogbo ọna lawọn igbimọ naa fi n wa ọna ti wọn yoo ṣe bọ lọwọ Ademọla Bakre, ẹni ti wọn lo n dawọn lọwọ kọ lati ṣiṣẹ wọn.

A ti ẹ gbọ pe laipẹ yi ni Ademọla naa ko awọn ọlọpaa atawọn babalawọ kan lọ si Aafin Gbagura lati yẹ Ifa wo lori ẹni ni yoo jọba naa, ti wọn si loun atawọn ti wọn jo n da ilu naa ru ni wọn wa nibẹ.

Lẹyin ti wọn pari ni wọn loo jade sita, to si sọ fawọn eeyan pe Sabure Babajide ni Ifa mu pe yoo jọba naa, ṣugbọn ti wọn jẹ ko ye e pe irọ lo n pa.

Eyi la gbọ pe o mu awọn igbimo naa sare lọọ ṣe ipade pajawiri lati yọ ọkunrin naa gẹgẹ bi alaga olori mọlẹbi to n yan ọba, iyẹn lọjọ kẹta oṣu yi, tii ṣe Tọside to kọja.

Leyin ipade naa lawọn aṣoju naa fẹnuko pe ki wọn yọ Ademọla nipo, ti wọn si tọwọ bowe lati fidi ẹ mulẹ.

Awọn ti wọn tọwọ bowe naa ni:Ọmọba Adeọla Adeyẹmi ti mọlẹbi Ijaade; Ọmọba Waheed Adeọsun to jẹ akọwe mọlẹbi Egiri; Ọmọba Sufian Ṣoẹtan ti idile Jamolu; Ọmọba Adam Ọpẹloyẹru ti idile Abọlade; ati Imaamu Jamiu Ogunwọọlu ti idile Ijaade.

Gbogbo akitiyan lati ba Ademọla Bakre sọrọ, ko le sọ tẹnu ẹ lo ja si pabo dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI