NITORI IGBA NAIRA, KẸHINDE GUN ỌRẸ RẸ PA L'AGBADO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 19, 2019

NITORI IGBA NAIRA, KẸHINDE GUN ỌRẸ RẸ PA L'AGBADO

Ko daju pe ọdọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Kẹhinde Adeoye yoo jade layọ lọgba ẹwọn pẹlu ofin ọdaran Naijiria to sọ pe ẹni to ba paayan, dandan ni ki wọn pa oun naa, to si fi han daju pe ile ẹjọ ba pada ri i pe Kẹhinde jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ẹwọn ni yoo ti lo eyi toku nigbesi aye rẹ, tabi ki wọn da ẹjọ iku fun un.

AWIKONKO gbọ pe ẹnikan lo fun ọlawunmi ni agboorun (umbrellla) lati tunṣe, to si fun Adeoye ni agboorun naa, tori pe iṣẹ ti baba ẹ n ṣe niyẹn, ko da, ti wọn loo tun fun un ni igba (200) naira, ko le tete ṣe e.

ọmọdun mọkandinlogun ni wọn pe Kẹhinde Adeoye ti wọn lo n kọṣẹ wẹda l'Agbado nigba ti wọn pe Lukman Ọlawunmi lọmọdun mẹtadinlogun toun kọṣẹ agolo.

Ọsẹ meji sẹyin ni wọn lẹni naa mu agboorun yi fun Ọlawunmi, to si jẹ pe latigba naa lo ti muu fun Adeoye pẹlu igba naira. Titi dasiko ti ọrọ buruku naa ṣẹlẹ ni wọn sọ pe Adeoye ko ṣe agboorun naa, to si ti na owo.

Inu ti wọn loo bi Ọlawunmi ni wọn lo fi gbe ija lọọ ba Adeoye ni ṣọọbu lati gba owo ati agboorun naa lọwọ é pe oun ko ṣe mọ, iyẹn lọjọ Tuside to kọja yi ni nnkan bi aago meje.

Nibi ti wọn ti  n fa ọrọ naa la gbọ pe Adeoye ti la irin mọ Ọlawunmi lori, to si mu idi lọ silẹ ko too wa eyin lu, to si jẹ Ọlọrun nipe.

Awọn ara agbegbe tọrọ ṣoju wọn la gbọ pe wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si lọọ muu. Titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan la gbọ pe Adeoye ṣi wa lọgba ẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI