Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ṣe ni Balogun
ilu Ẹgba, Oloye Sikirulai Atọbatẹlẹ; Baalẹ ilu Mowe, Oloye Tunde Ọjẹlade ati,
Alaaja Kudi Balogun to jẹ alaga ijọba ibilẹ idagbasoke ni Ọfada/Mọkọlọki lẹdi
apo pọ lati ta ilẹ ilu fawọn Ibo lati fi kọ ọja si, ati pe ọna ẹburu ni wọn fẹẹ
gba le awọn araalu kuro lori ilẹ Baba nla wọn.
AWIKONKO gbọ pe lati ọdun 2014
ni wahala naa ti wa nilẹ, nigba ti wọn sọ pe awọn agbaagba ilẹ Ibo kan ti wọn
tẹdo siluu Mowe, iyẹn awọn to n ta ọja nibẹ ni wọn pinu lati ra ilẹ naa, ki wọn
le fi kọ ọja ti wọn si, eyi to mu wọn lọọ gbe obitibiti owo fawọn eeyan naa pe
ki wọn le ta ilẹ fun wọn.
Gbogbo igbesẹ ti wọn ni wọn gbe
lati ra ilẹ naa lọwọ awọn to ni wọn lo ja si pabo, eyi to fa ki wọn lọọ gbe owo
nla fawọn Oloye ọja naa lati bawọn wa nnkan ṣe si i.
Oriṣiriṣi ipade la gbọ pe o ti
waye lati le bawọn eeyan naa sọrọ pe ki wọn ta ile ati ilẹ wọn fawọn to nilo ẹ,
ṣugbọn tawọn yẹn ko gba fun wọn. Ko pẹ ni wọn sọ pe ijọba ipinlẹ Ogun debẹ lati
ṣe ọna fun wọn, eyi gan an la gbọ pe wọn ri gẹgẹ bi anfaani lati fi gba ilẹ naa
lorukọ ijọba.
A tun gbọ pe awọn ileeṣẹ ti wọn
gbe iṣẹ ọja kikọ naa fun, iyẹn ileeṣẹ LUKASAI NIGERIA LIMITED ti bẹrẹ sii gba owo, miliọnu meji-meji
naira lọwọ awọn eeyan pe ki wọn ma a gba ṣọọbu ti wọn ko ti i kọ tan.
Nigba to n gba ẹnu awọn araalu fẹhonu
han, Kọmureedi Abọwaba Azeez to jẹ igbakeji alaga agbegbe Majẹobajẹ CDA jẹ ko
ye wa pe “Lọdun 2014 nijọba ipinlẹ Ogun de, ti wọn lawọn fẹẹ ṣe ọna fun wa,
ọpọlọpọ ile ati ṣọọbu wa ni wọn wo danu, ti wọn ko si fun wa loo gba ma binu
gẹgẹ bi ofin orileede yi ṣe laa kalẹ.
“Ile Baba to bi baba mi nile
akọkọ ti wọn maa kọ siluu Mowe yi. Nigba ti Gomina Amosun ṣe ọna naa debi kan,
la ṣakiyesi pe awọn kan wa a lẹ iwe sibi pe wọn tun fẹẹ wo ile wa, awọn ile ti
ko din ni aadọta.
“Latigba naa lati wa lori ẹ, ta
a si lọ sijọba ibilẹ wa, ta a si ranṣẹ pe alaga fidihẹ, Ọnọrebu Akintande,
ṣugbọn ko wa, lẹyin idibo lọdun 2015 la tun lọọ ba Ọnọrebu Jamiu Balogun Ṣoyọye
to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ati akọwe tẹlẹ, Ọnọrebu Ewedimu. Bẹẹ
latun pe Iyalọja ati Baalẹ.
“Nibi ipade ti wọn ba wa ṣe ni
wọn ti jẹ ko ye wa Gomina lo fẹẹ fi awọn ile ti wọn fẹẹ wo naa kọ ọja si, a si
beere lọwọ wọn pe eelo ni ijọba ti fun wa lori awọn ile wa ti wọn ti wo tẹlẹ, a
sọ fun wọn pe ijọba ko fun wa lowo gba ma binu nigba yẹn, iyẹn la fa titi ko
too di pe wọn pada jẹwọ fun wa pe kii ṣe ijọba ipinlẹ Ogun lo fẹẹ gba ilẹ wa.
“Oun lo wa tu aṣiri naa fun wa
pe awọn eeyan kan ni wọn fẹẹ ta ilẹ wa fawọn Ibo lati fi kọ ọja si, o si ki wa
nilọ pe bi a ko ba ti gbabọdi, ka duro gẹgẹ bi oṣuṣu ọwọ lati ja fun ẹtọ wa.
“Igba to tun di oṣu kejila ọdun
to kọja, wọn tun pe wa sile Baalẹ Mowe, ti wọn si ba wa sọrọ pe awọn kan ni wọn
fẹẹ fi ilẹ wa kọ ọja si, ai sọ fun wọn pe ilẹ ilu ni, orirun wa si ni, aaye ọja
ti wa lọtọ tẹlẹ, ko yẹ ko jẹ pe ilẹ ilu wọn yoo tun lo fun ọja.
“Oṣu to kọja ni wọn tun pada
wa, ti wọn bẹrẹ si i wo ile lọ lai sọ fun wa, eyi lo mu wa dide lati lọọ kilọ
fun wọn pe wọn ko gbọdọ wo ile kọja ilẹ ọja, nitori pe fẹnsi ti wa nibẹ, eyi to
pin ọja ati ilu sọtọọtọ, ti wọn si lawọn yoo wo. Wọn si lawọn gbọ.
“Igba ta a tun ri igbesẹ ti wọn
tun n gbe, lo jẹ ka dide lati sọrọ pe wọn ko gbọdọ wo ile wa, tori ki i ṣe ori
ilẹ ijọba lo wa. Idi ni yii ta a fi mu iwe ẹsun lọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa ni
Eleweran lati sọ nnkan to n dun wa lọkan, gbogbo awọn ti Kọmiṣana ọlọpaa pe
patapata lati wa a sọ tẹnu wọn ni wọn ko yọju nigba ti wọn ko ni iwe ẹri.
“Ki wahala ma ba a ṣẹlẹ, ati pe
a ko fẹ itajẹsile lo jẹ ka mu lẹta lọ si tẹṣan pe a fẹẹ fẹhonu han, ṣugbọn
tawọn ọlọpaa sọ pe a ko gbọdọ ṣe e. A ko fẹ ki wọn yan wa jẹ.”
Awọn araalu naa wa a rawọ ẹbẹ
sijọba Ibikunle Amosun pe ko dakun gba wọn lọwọ awọn to fẹẹ le wọn kuro lori
ilẹ baba nla wọn, ti wọn si fẹẹ gba a fawọn Ibo nitori pe awọn ko le gba ki Ibo
gba ilẹ wọn mọ wọn lọwọ nitori pe ajogunba awọn ni.
“A n rawọn ẹbẹ sijọba Ibikunle
Amosun, awa la dibo fun wọn ti wọn fi ṣe ijọba ọdun mẹjọ, awa naa la tun dibo
fun wọn ti wọn fi wọle sẹnetọ, ati pe ilu Mowe yi, abẹ Ogun Central lo wa. Ki wọn
si ba wa gbe igbesẹ to yẹ. Ki wọn lọ wa ọja wọn siwaju."
Nigba to n fesi si ọrọ naa,
ọkan lara awọn ọmọ Balogun Ẹgba, ti wọn wa nidi iṣẹ ọja kikọ naa, Oloye Lukmọn
Atọbatẹlẹ sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko ni i le fesi si ẹsun naa, ṣugbọn o jẹ ko
ye wa pe awọn ati ijọba ibilẹ lawọn jọ lọrọ, ko si nnkan to kan awọn pẹlu awọn
to n fẹhonu han.
Sibẹ, ohun tawọn eeyan n sọ ni
pe irọ lọkunrin naa n pa, nitori pe o mọ nnkan to n ṣe, ko si ni fẹẹ sọrọ to
maa koba a.
No comments:
Post a Comment