NITORI AṢỌ PENPE, AWỌN OMOGE WỌ GAU L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 1, 2019

NITORI AṢỌ PENPE, AWỌN OMOGE WỌ GAU L'ABUJA

Ileeṣẹ ajọ Social Development ni olu ilu orilẹede Naijiria ti sọ pe lootọ ni awọn yabo awọn ile-ijo kan nilu Abuja, lati pa iṣekuṣe run nitori bi awọn aṣẹwo ṣe pọ nilu Abuja.

Awọn ọmọ ikọ amuṣẹya ẹgbẹ naa to lọ ko awọn obinrin naa sọ pe awọn yabo awọn ile-ijo ati ile ọti nibi ti awọn ti ko awọn obinrin nikan nitori pe aṣọ pempe ni ọpọlọpọ wọn wọ.

Safiya Umar to jẹ ọga patapata fun ẹgbẹ naa sọ fun BBC pe awọn ko ni la oju silẹ ki awọn ọmọbinrin naa maa ṣe boṣe wu wọn.

O ni ''Ko dara ka fi aaye gba awọn ọmọbinrin wa lati maa ṣe nkan ti ko tọ tabi ta ara awọn nile ijo. Koda, awọn ile ijo naa ko ba ofin mu nitori pe aarin adugbo ti awọn eniyan n gbe ni wọn wa."

''Eyi kii ṣe ọrọ ofin rara. Ọmọ ilẹ Afrika ni wa, awọn obinrin si gbọdọ maa hu iwa to dara.''

O ṣalaye pe awọn ọmọbinrin tilẹ maa n bọ ara wọn si ihoho nile ijo, awọn si fẹ ẹ ri i daju pe ilu Abuja ni oṣuwọn iwa to tọ.

Wọn fi ipá mu wa lati sọ pe a jẹbi
Awọn ọmọbinrin naa ti wọn gbe lọ sile ẹjọ alagbeka kan to wa ni adugbo Old Parade Ground nilu Abuja ni ko ni agbẹjọro kankan to ṣoju wọn bi adajọ ṣe n ka ẹsun wọn sita.

Niṣe ni pupọ lara wọn dahun pe ''awọn jẹbi, nigba ti adajọ beere pe ''ṣe ẹgba pe lootọ ni ẹ n ta ara yin, ti ẹ si fi n da alaafia ilu laamu, leyi to tako ofin ilu Abuja."

Ọjọ Ẹti mọju ọjọ Abamẹta ni wahala bẹrẹ ninu aye awọn ọmọbinrin naa nigba ti awọn oṣiṣẹ alaabo yabo awọn agbegbe kan nilu Abuja.

Ileeṣẹ ọlọpaa naa sọ pe ẹ̀sìn meji to gbajumọ ju ni Naijiria
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ ọlọpaa naa f'esi si ọrọ naa pe ẹ̀sìn meji to gbajumọ ju ni Naijiria tako iṣẹ aṣẹwo ṣiṣe

Ọkan lara awọn ọmọbinrin naa ti a fi orukọ bo ni aṣiri, sọ pe oun sin ọrẹ oun kan lọ gbe akara oyinbo fun onibara rẹ kan ni wọn mu awọn nigba ti awọn n fẹ ẹ jade lati maa lọ sile.

Ọmọbinrin naa sọ pe ''wọn sọ fun wa pe ti a ko ba sọ pe lootọ la jẹbi, ọdọ awọn ni a o wa fun oṣu mẹfa. Ibẹru lo si mu ki a gba pe a jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wa.''

Adajọ naa dajọ pe wọn jẹbi, o si dajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun wọn tabi ki wọn o san ẹgbẹrun maarun Naira owo itanran. Ṣugbọn nigba ti ẹbẹ pọ, adajọ din ẹwọn naa ku si oṣu kan, tabi ẹgbẹrun mẹta fun owo itanran.

Botilẹ jẹ pe ko si ofin kankan ni Naijiria to tako wiwọ aṣọ penpe, abala karundinlogoji ofin ilu Abuja to tako ìrìn ti ko ba ofin mu ni wọn fi ka ẹsun si wọn l'ẹsẹ.

Diẹ lara awọn ọmọbinrin ti ikọ̀ amuṣẹya naa mu lo fi ẹsun kan wọn pe "wọn fi ipa ba diẹ lara wọn lopọ."

Ṣugbọn, ọga patapata fun ẹgbẹ SDS, Arabinrin Safiya sọ pe irọ ni ẹsun naa.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI