NGIJ: ILEEṢẸ ỌLỌPAA GBE ORIYIN FUN GOMINA YAHAYA BELLO NITORI ETO AABO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 9, 2019

NGIJ: ILEEṢẸ ỌLỌPAA GBE ORIYIN FUN GOMINA YAHAYA BELLO NITORI ETO AABO

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi sọ pe iṣejọba Gomina Yahaya Bello gbajumọ eto aabo, ti ko si si nnkan to n jẹ wahala nitori pe lara nnkan to jẹ ijọba naa logun ju niyẹn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Williams Ovye Aya lo sọrọ naa lonii Tọside lasiko ti ikọ ẹgbẹ oniroyin to n ṣiṣẹ iwadii kulẹkulẹ lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Guild of Investigative Journalists ba a ni alejo nileeṣẹ wọn to wa niluu Lọkọja, ipinlẹ Kogi.

Ọgbẹni Ovye Aya jẹ ko di mimọ pe Gomina ipinlẹ naa, Alaaji Yahaya Bello ko fi nnkankan dun ileeṣẹ ọlọpaa, to si jẹ pe gbogbo nnkan ti wọn nilo nijọba pese lọna to peye, eyi to n mu ki iṣẹ rọrun fun wọn.

Ọkunrin naa ni titi kan mọto, atawọn ohun elo nijọba pese fun ti eto aabo ipinlẹ naa si n lọ geerege ju ti saa iṣakoso to kọja lọ, koda, tawọn araalu naa tun le jẹri si i.
 
Nigba to n sọrọ, Aarẹ fidihẹ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Wale Abydeen to lewaju awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọ pe ohun tawọn eeyan n sọ kaakiri igboro ni pe ko si alaafia nipinlẹ naa, ati pe awọn iwe ti ko din lẹgbẹrun mẹwaa to kun fun oriṣiriṣi ibeere lawọn ti pin kaakiri ijọba ibilẹ mọkanlelogun to wa nipinlẹ naa

O wa a dupẹ lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa fun anfaani to fun wọn lati gba wọn lalejo, to si tun ṣeleri pe gbogbo bi nnkan ba ṣe n lọ lawọn yoo maa fi to wọn leti.

Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe awọn ṣi n tẹsiwaju lati lọọ ṣepade pẹlu awọn oloye, lọbalọba, awọn oṣiṣẹ fẹyinti, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ atawọn ẹka ileeṣẹ ijọba lati le ri okodoro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI