Gomina Abiọla Ajimọbi tipinlẹ Ọyọ
ti sọ ọ nita gbangba pe oun ti ṣetan fun ijọba to n bọ lọna yi lati gbe oun, bi
wọn ba ṣewadi ijọba oun, ti wọn si ri i pe oun jale.
Nibi eto idanilẹkọọ ita-gbangba
kan ti ajọ Society for Peace Studies and Practice ṣagbekalẹ ni gbọngan Ṣubomi
Balogun to wa ninu ọgba ile ẹkọ fasiti tiluu Ibadan, iyẹn UI to wayẹ lọjọ
Tọside ana ni Gomina Ajimọbi ti sọrọ naa.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Ajimọbi sọ
pe “Titi di asiko to gbẹyin ninu ijọba yi la fi maa ṣiṣẹ. Emi o bikita si ohun
tawọn kan n sọ kaakiri. Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ lonii, iṣakoso ṣi ni ọjọ
mejidinlogun atawọn wakati meloo kan, ko too tan.
“Bi wọn ba debẹ, ẹ jẹ ki wọn fagile
awọn akanṣe iṣẹ ti a gbe jade ta a si ti bu ọwọ luu. Ẹ jẹ ki wọn ṣewadii wa, bi
wọn ba si ri i pe a ti jale, ẹ jẹ ki wọn gbe wa.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yi Gomina
tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde fẹsun kan Gomina Ajimọbi pe o
gbe iṣẹ jade lọna aitọ, iṣẹ na ti ọwọ ẹ ko din ni ọọdunrun biliọnu naira lọjọ
kan ṣoṣo, to si fọwọ sọya pe oun ṣewadi bi iṣẹ naa ṣe jẹ nigba toun ba gbakoso.
No comments:
Post a Comment