Manchester City jẹwọ pe ẹni a
ba ni aba ni Baba fun Liverpool pẹlu bi wọn ṣe din dundun iya mẹrin si odo fun
Brighton.
Gundogan lo jẹ goolu kẹrin pẹlu
gbe silẹ gba sile to gba wọ ile Brighton.
Kete ti goolu naa wọle ni
gbogbo agbo daru ti awọn alatilẹyin City si bẹrẹ si ni jojo ayọ.
Abala Ikeji ti bẹrẹ
Nigba ti a ba fi ri iṣẹju
márùndínláàdọ́ta tabi ju bẹ lọ diẹ a o mọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo gba ife ẹyẹ
Premiership ti ọdun yi.
Laarin Liverpool ati Manchester
City ni dugbẹ dugbẹ yi n fi si amọ ko ti daju ibi ti yoo ja si.
Bi abala Ikini ti ṣe lọ
Nkan kọkọ fẹ jọbi pe ko ṣẹnu re
fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ninu ifẹsẹwọnṣẹ to n lọ lọwọ ninu idije
Premiership.
Amọ nigba ti awọn agbabọọlu wọn
yoo fi ṣara giri, wọn fi goolu meji si ookan ti Brighton fi ẹsẹ rinlẹ lori
afara liigi Premiership.
Akẹgbẹ wọn Liverpool n tọ wọn
lẹyin pẹlu bi wọn ti ṣe fi goolu kan ju Wolves lọ.
Sadio Mane lo jẹ goolu naa fun
Liverpool.
Bi nnkan ti ṣe ri bayi,
Manchester City lo jọ bi pe wọn yoo gba ife naa.
Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ miran to n
waye wọn yi ni esi ti a ri ni abala kini
Brighton1 Man City 2
Burnley 0 Arsenal0
Crystal Palace 3 Bournemouth 0
Fulham 0 Newcastle 2
Leicester0 Chelsea 0
Liverpool 1 Wolves 0
- BBC
No comments:
Post a Comment