L'ỌSAN AAWẸ, ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ BAṢIRU TO FẸẸ FIPA BA NỌỌSI SUN L'ỌSIBITU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 15, 2019

L'ỌSAN AAWẸ, ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ BAṢIRU TO FẸẸ FIPA BA NỌỌSI SUN L'ỌSIBITU

Ẹrin keekeekee lawọn eeyan n fi ọdọmọkunrin ẹni ogun (20) ọdun kan, Baṣiru Yahaya rin nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Kano tẹ ẹ, lasiko to fẹẹ fipa ba nọọsi kan sun lọsibitu.
Wọn ni gbogbo akitiyan Baṣiru lati ba nọọsi ta a forukọ laṣiri ni ọsibitu aladani kan to wa ni Taludu Quarters, ijọba ibile Gwale lo ja si pabo, nigba tiyẹn ki ọbẹ mọlẹ, to si fi gun ara rẹ lọrun lọjọ Tuside ana.

A gbọ pe ki Baṣiru ma ba a ri ibaṣepọ naa ṣe lo mu ki nọọsi naa fi ọbẹ gun ara rẹ lọrun, to si jẹ pe diẹ lo ku ki ọlọjọ de. Ariwo ti wọn ti nọọsi naa pa lo mu kawọn eeyan to wa nitosi dide lai yọju, ti wọn si nnkan to ṣẹlẹ.

Lẹsẹkẹsẹ lawọn eeyan ti ranṣẹ sawọn ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI