Ninu atẹjade ti Ajọ SERAP gbe
lede, Kọlawọle Oluwadare ni Fashọla fi ṣọwọ si wọn gẹgẹ bi ilana ofin to rọ mọ
‘Information Act’ ti orilẹede Naijiria to fọwọ si wi pe ti ọmọ Naijiria ba bẹrẹ
iwadii kikun lori isẹlẹ, wọn gbọdọ fi lede.
Iwe ti wọn fi ransẹ si wọn naa
fihan wipe "Pow Technologies Limited" to kalẹ si ilu Abuja kọ lati ko
irinsẹ ti wọn fi n se ayẹwo ina ninu ile ati kaakiri ile isẹ NAPTIN ti wọn san
miliọnu mọkandinlogoji fun ninu miliọnu mẹtadinlaadọrun, amọ ti wọn kọ lati ko
irinsẹ naa wa.
Gẹgẹ bi ile isẹ to n risi ọrọ
ile gbigbe ati isẹ se sọ, ọdun 2014 ni wọn ti gbe isẹ naa fun wọn, ti o si jẹ
pe mẹtala ninu mọkandinlogun isẹ ti wọn gba ni wọn se.
Ajọ SERAP naa ni awọn ni asẹ
lati ri iwe naa nitori asẹ ti awọn gba lati ile ẹjọ giga ni ilu Eko ni Osu
Keji, ọdun 2019.
- BBC
No comments:
Post a Comment