LẸYIN ỌPỌLỌPỌ ỌDUN, WỌN LẸGBẸ OṢERE TAMPAM DARIJI BABA WANDE ATI LERE PAIMỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 8, 2019

LẸYIN ỌPỌLỌPỌ ỌDUN, WỌN LẸGBẸ OṢERE TAMPAM DARIJI BABA WANDE ATI LERE PAIMỌ

Gbogbo awọn to gbọ nipa nnkan to n lọ nigboro laarin ẹgbẹ oṣere tiata TAMPAN ati ANTP, ni wọn sọ pe ọrọ buruku gbaa ni ati pe kin ni awọn ẹgbẹ oṣere TAMPAN n fi ara wọn pe.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lawọn agba oṣere atawọn Oloye ẹgbẹ oṣere TAMPAN lawọn ti dariji awọn agba ọjẹ nidi iṣẹ naa, Alaaji Kareem Adepọju tawọn eeyan mọ si Baba Wande ati Oloye Lere Paimọ tọpọ mọ si Ẹda Onile-Ọla lati maa lo wọn ninu fiimu ti wọn ba n ṣe.

Lọgba LTV niluu Eko lọrọ naa ti taa si wa leti nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ laaarin ara wọn, ko da wọn sọ ọ debi pe laipẹ yii ni Baba Wande ṣẹṣẹ kopa ninu fiimu tọmọ ẹgbẹ oṣere TAMPAN ṣe.

Bẹ o ba gbagbe ni nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin ni Dele Odule to jẹ Aare ẹgbẹ oṣere TAMPAN tẹlẹ paṣẹ pe wọn ko gbọdọ pe ọmọ ẹgbẹ oṣere ANTP kankan sinu iṣẹ tawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ ba n ṣe.

Idi niyii ti wọn fi pa awọn agba oṣere naa ti, to jẹ pe wọn sọ ọ di ogun laaarin ara wọn, ko da nibi ti wọn baa de, aimọye awọn ọrẹ ni wọn di ọta nitori igbesẹ ti wọn gbe naa.

Bo tilẹ jẹ pe nigba to ku diẹ ki saa Dele Odule pari ni iyatọ ti n de ba ẹgbẹ mejeeji ti wọn si ti n bara wọn ṣe, bi bara wọn ṣe naa, ko debi iṣẹ ti wọn ṣe.

Ṣugbọn nnkan to ya awọn to gbọ nipa igbesẹ naa lẹnu ni pe o ṣe jẹ pe Baba Wande ati Lere Paimọ nikan ni agba ti wọn sọ pe awọn dariji lati maa bawọn ṣiṣẹ papọ, ati pe iru ẹṣẹ wo ni wọn ṣe wọn tẹlẹ, ti wọn fi n febi pa awọn baba naa.

Iwadii tun fi ye wa pe awọn agba oṣere ti wọn tiẹ wa pẹlu wọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ pọ, o di fiimu meloo ti wọn pe awọn agba naa si ati pe njẹ wọn tiẹ ranti wọn.

Njẹ ohun to dara ni kawọn TAMPAN maa sọ pe awọn dariji awọn to gbẹ kanga iṣẹ naa fun wọn. Ọkan lara awọn agba oṣere tiata to wa ni Eko sọ foniroyin wa pe iran ni ọrọ wọn ṣugbọn o dawọn loju pe aṣesilẹ ni abọwaba, gbogbo nnkan ti wọn ba ṣe fawọn agba oṣere lawọn naa yoo gba.

- BO ṢE RI

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI