LẸYIN ỌDUN KẸTA: WỌN YAN ỌBA TUNTUN NILUU ỌJỌWỌ IJẸBU-IGBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 18, 2019

LẸYIN ỌDUN KẸTA: WỌN YAN ỌBA TUNTUN NILUU ỌJỌWỌ IJẸBU-IGBO

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo ọmọ bibi ilu Ọjọwọ niluu Ijẹbu-Igbo kaakiri agbaye ni wọn ti n pada siluu wọn bayii fun ti ayẹyẹ igbade Ọba tuntun to fẹẹ waye lọjọ Fraide ọsẹ to m bọ, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi.

Ohun ta  agbọ ni pe lati bi ọdun mẹta sẹyin ni Kabiyesi ana fun ilu naa ti waja, to si jẹ pe latigba naa lawọn eeyan ti dide lati du ipo naa, ko too di pe gbogbo ilu panupọ lati fa Ọmọba AbdulRasheed Abayọmi Banjọ kalẹ gẹgẹ bi Olokine tiluu Ọjọwọ, Ijẹbu-Igbo lati maa ṣe olori wọn.

Ninu lẹta ti ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun fi sita laipẹ yi, eyi ti ẹda lẹta naa tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn yoo gbe ade fun Ọmọba AbdulRasheed Banjọ nibamu pẹlu ofin to rọ mọ oye jijẹ, tọdun 2006.

Inu ọgba ile ẹkọ Girls Grammar School to wa niluu Ijẹbu-Igbo la gbọ pe ayẹyẹ naa ti fẹẹ waye, bẹrẹ lati aago mejila ọsan, ti wọn si lawọn eeyan jankanjankan ni yoo peju sibẹ lọjọ naa, ko da ti wọn lawọn ololufẹẹ Kabiyesi tuntun naa ti n fi ẹbun oriṣiriṣi ranṣẹ, ki ọjọ naa le larinrin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI