LẸYIN ỌDUN KẸSAN-AN, AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA N ṢE IRANTI OLOOGBE MUSA YAR'ADUA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 5, 2019

LẸYIN ỌDUN KẸSAN-AN, AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA N ṢE IRANTI OLOOGBE MUSA YAR'ADUA

Iku n pani, ilẹ n jẹ'yan. Ọjọ Aiku, ọjọ karun un oṣu karun un ni o pe ọdun mẹsan-an gerege ti aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Umaru Musa Yar'adua re iwalẹ asa.

Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lo n ṣedaro aarẹ ana. Ninu wọn ni oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar wa.

Atiku to msọrọ lojun opo Twitter ni aarẹ tẹlẹ ri, Yar'adua jẹ alaanu eeyan, bẹẹ lo si fẹran orilẹede rẹ nigba to wa loke eepẹ.

Atiku gbadura pe ki Ọba oke ko dẹlẹ fun ẹni 're to lọ.

Ninu ọrọ tiẹ, aarẹ ana to tun figba kan jẹ igbakeji fun Aarẹ Yar'adua, Goodluck Jonathan ṣapejuwe Yar'Adua bi ọrẹ, iyekan ati ọga.

Jonathan ni Yar'Adua jẹ olori ti ko ni imọ tara ẹni nikan, bakan naa lo ṣapejuwe rẹ gẹgẹ ẹniti o maa n gbiyanju nigba gbogbo lati ri wi pe ifẹ orilẹede Naijiria siwaju ifẹ ọkan rẹ.

Adari ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Bukọla Saraki naa ko gbẹyin ninu awọn to n ṣe iranti aarẹ to lọ.

Saraki ni iwe rere ti Yar'Adua wu nigba to jẹ aarẹ Naijiria ti di ohun manigbagbe, bẹẹ lo gbadura pe ki aanu Eleduwa maa baa nibi kibi to ba wa.

Sẹnẹtọ Shehu Sani naa sọrọ iwuri nipa Yar'Adua, o ni aarẹ to lọ jẹ olotitọ eniyan ati oloṣelu ti kii figba kan bọkan ninu.

Sẹnẹtọ Saniu fikun ọrọ rẹ pe onirẹlẹ eniyan ni Yar'Adua jẹ, bakan naa lo gbadura pe ki Eleduwa Alijana ṣẹsan 're fun un.

Ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2010 ni Aarẹ Umaru Musa Yar'Adua jade laye.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI