Bi ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Kelvin Isaiah ba bọ ninu wahala to ko ara rẹ si yi, to si tun pada sidi ole jija, a jẹ pe ko nifẹ ara rẹ mọ, to si n wa ọna lati pada sọrun alakeji to ti wa.
Ọjọ Sande ana ni nnkan bi aago mẹsan ku oogun iṣẹju la gbọ pe Kelvin ati ọrẹ rẹ toun ti na papa bora lọọ fibọn ja foonu Techno W2 gba lọwọ ọdọmọbinrin kan, Chioma Damilọla lagbegbe Akenfa 3 to wa ni Yenagoa.
A gbọ pe bi wọn ṣe gba foonu naa tan, ni wọn yọ SIM CARD lee lọwọ, eyi lo mu ki Damilọla lọọ fọrọ naa to awọn Fijilante leti, ti wọn si le awọn ọdaran naa mu, ṣugbọn to jẹ pe Kelvin nikan lọwọ tẹ.
Alubami la gbọ pe wọn kọkọ fi ti ẹ ṣe nigba tọwọ tẹ ẹ, ko too di pe wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
No comments:
Post a Comment