Beeyan ba ri bi gbajumọ sọrọ
ori redio ati tẹlifiṣan nni, Babatunde Okunade tawọn eeyan tun n pe ni Ọmọba ṣ
e n sọrọ, to si sọ pe kijọba apapọ orileede Naijiria, labẹ Ọgagun Muhammadu
Buhari tete wa nnkan ṣe si ọrọ ebi to n pawọn araalu, paapaa oun lasiko yi,
nitori pe ọrọ ebi naa ti n kọja oju tawọn eeyan fi n wo o, eeyan yoo fẹẹ le maa
ba a sunkun.
Ọmọba Okunade to tun jẹ ilumọn
ọn ka adẹrinpoṣonu naa to filuu Abẹokuta ṣegbugbe lo sọrọ naa lori fọnran
oni-ṣẹju mẹfa kan to gbe sori ayelujara laipẹ, pe ki wọn ba oun fi ranṣẹ si
Aarẹ Buhari, ko le tete wa nnkan ṣe.
Ọkunrin sọrọsọrọ naa to ti gba
oriṣiriṣi aami ẹyẹ fun ipinlẹ Ogun lẹka ere idaraya yi ni ọna kan ṣoṣo tijọba
Buhari le gba yanju iṣoro airi ounjẹ jẹ tawọn araalu n koju ni lati gbe igbimọ
ti yoo ri sọrọ ounjẹ dide, ati pe ẹni naa ko gbọdọ jẹ olowo, bi ko ṣe lara awọn
ti ebi n pa, nitori pe ẹni naa gan an lo le mọ ibi ti bata ti n ta awọn eeyan
lẹsẹ.
Ninu ọrọ rẹ ninu fọnran naa lo
ti sọ pe “Mo ki gbogbo ẹyin ti ẹ n wo mi, Babatunde Ọmọba Okunade lorukọ mi, ẹ
ma binu pe mo fẹẹ gba diẹ ninu asiko yin. Ẹ gbiyanju nitori Ọlọrun, ẹ ba mi fi
fọnran yi ranṣẹ kaakiri, ko le awọn ibi ti mo fẹ ko de, iyẹn ọdọ Aarẹ Buhari.
“Ẹ pin in kaakiri ẹrọ ayelujara
bii Twitter, Facebook, WhatsApp, Instagram atawọn min in ti ẹ ba mọ. Ko si ẹni
to le sọn awọn nnkan fun yin yatọ si awa mẹkunu, awọn minisita, gomina ko sọ ọ.
“Aarẹ wa, mo fẹ ki ẹ mọ pe lati
2015 ti ẹ ti wa lori oye, ilu le gidi gan an ni, boya ẹ fẹẹ gbọ, tabi ẹ kọ, mo
ni lati sọ okodoro ọrọ. Nnkan le, nnkan ko si rọrun fawọn araalu rara. Awa ti
iya n jẹ la le mọ. Ebi n pa wa, ẹlomin in le sọ pe ebi ko pa oun, ṣugbọn emi
Babatunde Okunade n fi asiko yi sọ fun un yi pe ebi n pa mi o.
“Wọn le sọ pe mi o niṣẹ, iṣẹ
kan ṣaa ni mo n ṣe bọ tẹlẹ, bi mo si ṣe wa yi, mi o kii ṣe ọmọ kekere mọ, o si
ti logun ọdun ti mo ti wa nidi iṣẹ yi, iṣẹ yi naa si ni mo n ṣe ti mo fi n bọ
ara mi ati ẹbi mi tẹlẹ. Mi o ni ajọṣepọ pẹlu oloṣelu kankan tori pe opurọ ni
gbogbo wọn, oloṣelu ko le sọ otitọ ọrọ fun un yi laye yi, ṣugbọn awa ti a le
sọrọ naa re e, ẹ ko si le ri wa nidi oṣelu, nitori pe a ko ni le purọ fawọn
eeyan, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan wa naa ko fẹ otitọ.
“Aarẹ wa, lati 2015 ti ẹ ti de
ni ebi ti n pa awa ọmọ Naijiria gidigidi gan an ni o. Iya to tiraka ran ọmọ ẹ
nileewe, tọmọ naa si pada jade ileewe, ti ko wa ri iṣẹ fi ṣe, bawo ni ọmọ na ko
ṣe ni i jale, ti ko ni lọọ darapọ mọ ẹgbẹ buruku, tabi ko ṣe Yahoo lati le jẹ
ki mama ẹ naa kuro ninu iṣẹ ati oṣi.
“Ki i ṣe ẹjọ gbogbo awọn ọmọ to
n ṣe iṣẹ aṣẹwo rara, iya lo sun wọn debẹ ki i ṣe pe o dun mọ wọn ninu, awọn naa
fẹẹ jẹun, wọn fẹẹ mu, wọn si fẹẹ wọ aṣọ, nitori pe iṣẹ ni ko si, bi ẹyin naa ba
wo bi a ṣe pọ to, diẹ la fi din ni miliọnu lọna igba (190million).
“Igbimọ gbọdọ wa to maa ri si
ọrọ ounjẹ, ki i ṣe awọn olowo lẹ maa yan nitori pe iya ko jẹ wọn, Olowo ko le
sọ nnkan to n ṣe mi, emi ni mo mọ ibi ti bata ti n ta mi lẹsẹ. Ẹ jẹ ka pe awọn
eeyan lori bi ounjẹ ṣe maa pọ rẹpẹtẹ niluu. Awọn ti wọn n lọ siluu Oyinbo sọ pe
awọn naa n tiraka lati lowo, ṣugbọn iya ounjẹ ko jẹ awọn nitori pe ijọba pese
ounjẹ fun wọn.
“Ebi lo le ọpọ awọn eeyan de
ibi ti wọn ti n ji eeyan gbe beere owo, a ko sọ pe nnkan ti wọn n ṣe dara,
ṣugbọn ti ebi ba kuro ninu iṣẹ, iṣẹ ti buṣe o. Awọn kan ti n ẹ sọ pe ki n ma ṣe
fọnran yi, pe ijọba maa mu mi, wọn a si pa mi, ṣugbọn mo nigbagbọ pe ko sẹni to
le pa ẹni ti Ọlọrun ko pa.
“Babatunde Okunade lorukọ mi, ẹ
ma daamu lati wa mi kaakiri, mo wa larọwọto yin bi ẹ ba fẹẹ ri mi lati ṣalaye
lẹkunrẹrẹ siwaju sii. Ebi n pa mi o.”
Ọpọ awọn ti wọn wo fonran yi lo
ṣi n ṣe ni kaayefi pe bawo ni gbajumọ sọrọsọrọ ṣe maa n sọ iru nnkan to to
bayii sijọba, ṣugbọn oun tawọn kan n sọ ni pe ebi to n pa ọkunrin naa lo sun un
debẹ, ati pe nnkan ko fi bẹẹ dan mọnran fun un mọ lasiko yi, to si nilo
iranlọwọ gidi.
No comments:
Post a Comment