Ṣe ni idunnu gba ọkan awọn ọmọ
atawọn olugbe ipinlẹ Ogun lọjọ Sande ana, paapaa awọn to wa niluu Ilaro lakoooko
ti Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọmọba Dapọ Abiọdun n sọrọ, to si sọ awọn eto
oriṣiriṣi to ni fawọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa l’ẹka eto ẹkọ.
Ṣọọṣi All Saints Anglican to wa
niluu Ilaro ni Gomina tuntun naa ti sọrọ yi lasiko to n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun
anfaani lati di Gomina nipinlẹ Ogun, nibẹ lo ti ṣeleri pe oun yoo mu ayipada
rere de ba ipinlẹ naa laarin ọgọrun ọjọ to ba de ipo.
“Ọjọ Ọlọrun lonii jẹ, kii ṣe
ọjọ temi tabi ẹnikẹni rara. Ohun ti a n ṣe lonii, kii ṣe pe boya a n ṣayẹyẹ mi,
tabi ti igbakeji mi, tabi ti mọlẹbi mi, tabi gbogbo awa ti ẹ dibo yan; ohun ta
a n ‘se ni pe, a n ṣayẹyẹ Ọlọrun, ati ij’olotitọ ọlọrun ninu aye wa.
“Ọlọrun ti jẹri ara rẹ ninu aye
wa pe Ọlọrun alagbara loun, tori pe oun ni Ọlọrun, oun si ni yoo maa jẹ Ọlọrun,
nitori pe eniyan ko le di Ọlọrun lailai. Gbogbo wa la mọ pe to ba jẹ pe eniyan
ni, mi o ni lanfaani lati duro niwaju yin loni in. Mo ti jẹjẹ pe maa lo ipo yi
lati fi gbe iṣẹ Ọlọrun ga, kii ṣe nipinlẹ yi nikan, bi ko ṣe kaakiri agbaye.
“Mo tun fẹẹ jẹjẹ gẹgẹ bi mo ṣe
n maa n sọ lọpọ igba pe ipinlẹ yi, maa jẹ ko jẹ ti gbogbo wa. Ijọba yi yoo jẹ
ijọba gbogbo eeyan, afojusun ti yoo mu ijọba gidi wa laaye la ni, aaye si ti ṣi
silẹ fawọn ileeṣẹ aladani ati ti gbogboogbo ti wọn ba fẹẹ fọwọsowọpọ pẹlu wa.
“Mo fi n da a yin loju pe, a ko
ni mu idagbasoke ba ipinlẹ yi lati fi pa awọn eeyan lara. O dara lati ni
olu-ipinlẹ gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ, ṣugbọn sibẹ, o ṣe pataki fawọn olugbe ti wọn jẹ
oniṣowo ati agbẹ lati le gbe ọja wọn kuro nibi ti wọn ba wa lọ sibomin in bii
ọja lai ni’daamu.
“Gẹgẹ awọn nnkan to wa nilẹ
atawọn nkan ta a ti foju ri, a maa gbe eto ṣiṣẹ opopona kekeeke ati nnla, to fi
mọ awọn agbegbe igberiko kaakiri ipinlẹ Ogun fawọn aladani. O ṣeni laanu pẹlu
ipo tawọn opopona wa wa lonii, ohun ti a si fẹẹ gbiyanju lati ṣe ni pe, bi mo
ti ṣe wo bawọn opopona kaakiri naa ṣe ri, a si ti gbe awọn eeyan dide lati lọọ
mọ iye tawọn opopona naa yoo na wa lati tun wọn ṣe.
“A ti n fẹẹ gbe ẹka ileeṣẹ
ijọba to n ri si atunṣe opopona ti a mọ si OGROMA dide pada, idi ẹ si ni lati
maa dide tun awọn opopo na wa ṣe. A ko nii daa ṣe, gbogbo yin naa lẹ maa da
sii.
“Bẹẹ la tun ti ri ipo tawọn
ọsibitu wa wa, pẹlu awọn ile-ẹkọ alakọbẹrẹ, eyi ti yoo jẹ pe laarin ọgọrun ọjọ
wa lori ipo, opopona, eto ẹkọ ati ọsibitu la maa gbajumọ. A ti de agbegbe
Agbara, a si ri ipo ti opopona naa wa, tori pe ibẹ gan an ni agbara ipinlẹ yi
wa lori eto ọrọ aje, ta a si gbọdọ ṣe nnkan sibẹ.”
Lara awọn to wa nibi eto naa
ni, Alake tilẹ Ẹgba; Akarigbo tilẹ Rẹmọ, Olu-Ilaro, Tolu Ọdẹbiyi, Suraj Adekunbi,
Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ, Ọnọrebu Oluọmọ, Aṣoju Olowu tiluu Owu, Sẹnetọ Gbenga
Kaka, Sẹnetọ Yayi, Ọnọrebu Abiọdun Akinlade, Ọnọrebu Ẹlemide Olumide, Olu-Itori
atawọn min in.
No comments:
Post a Comment