ILE ẸJỌ KOTẸMILỌRUN DA ẸSUN TI WỌN FI KAN DAPỌ ABIỌDUN NU, LO BA LOUN YOO YẸ GBOGBO IṢE TI GOMINA AMOSUN N ṢE LỌWỌ WO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 7, 2019

ILE ẸJỌ KOTẸMILỌRUN DA ẸSUN TI WỌN FI KAN DAPỌ ABIỌDUN NU, LO BA LOUN YOO YẸ GBOGBO IṢE TI GOMINA AMOSUN N ṢE LỌWỌ WO

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta, Ko sọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lorileede Naijiria, paapaa awọn ọmọ ipinlẹ Ogun to gbọ bi ile ẹjọ kọtẹmilọrun to fikalẹ siluu Abuja ṣe da ẹjọ ti wọn pe lati fẹsun kan Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọmọba Dapọ Abiọdun pe ko niwe ẹri onipele mẹwaa, ati pe ko kopa lati sin orileede baba rẹ nu, ti ko nii fẹsẹ ra ijo.

Ana, ti i ṣe Monde nile ẹjọ naa sọ pe ẹjọ ti wọn pe lati fi tako Ọmọba Dapọ Abiọdun naa ko lẹsẹ nilẹ, nitori pe ayederu iroyin ni gbe wa sile ẹjọ lati ṣiṣẹ le lori.

Bẹ ba gbagbe, o ti ṣe diẹ tawọn alatako ti n sọ pe Ọmọba dapọ Abiọdun ko fun ajọ INEC lawọn iwe ẹri to ni, ati pe ayederu iwe ẹri lo fi silẹ, eyi ti wọn loo tako ofin ajọ eleto idibo, paapaa ofin orileede yi.

Aarẹ ile ẹjọ naa, Onidajọ Datti Yahaya lo paṣẹ naa pe oun da ẹjọ naa nu, nitori pe otitọ fi foju han.

Ninu iroyin min in to tun fara pẹẹ ni pe, Gomina tuntun naa, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti sọ pe dandan ni koun yẹ awọn iṣẹ akanṣe ti Gomina Amosun n ṣe lọwọ wo, titi dori eyi to ṣe gbẹyin, iyẹn boun ba de ọfiisi lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yi.

Bẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni Gomina Amosun sọ pe oun yoo gba awọn ẹgbẹrun kan oṣiṣẹ siṣẹ koun too kuro nijọba. Gomina Amosun sọ pe ki i ṣe pe oun dee de fẹẹ gbawọn oṣiṣẹ tuntun bi ko ṣe pe awọn to yege ninu awọn ẹgbẹrun marun to kopa ninu idanwọ lọdun kan le diẹ sẹyin loun fẹẹ gba siṣẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Tunde Ọladunjoye fi sita lana, lo ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe awọn iṣẹ nikan nijọba Dapọ Abiọdun yoo yẹ wo, bi koṣe tawọn Ọba tuntun to tun gbe ọpa aṣẹ fun un, bo ya loootọ ni wọn kun oju oṣuwọn.

Ọladunjoye sọ pe awọn ko nii gba igbesẹ ti Gomina Amosun fẹẹ gbe naa lati gba awọn eeyan siṣẹ nigba to ku asiko diẹ kijọba ẹ kogba wọle, ati pe ọna tiko ba ofin mu lo fi fawọn eeyan nigbega apapandodo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI