IJỌBA IPINLẸ KANO ṢE IGBEYAWỌ FAWỌN ẸGBẸRUN KAN AABỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 4, 2019

IJỌBA IPINLẸ KANO ṢE IGBEYAWỌ FAWỌN ẸGBẸRUN KAN AABỌ

Lasiko ti ẹ n ka iroyin yi, ayẹyẹ nla lo n ṣẹlẹ lọwọlọwọ nipinlẹ Kano, pẹlu bijọba ipinlẹ naa ṣe n ṣayẹyẹ igbeyawo fawọn tọkọ-tiyawo ti ko din ni ẹgbẹrun kan ataabọ (1500) kaakiri ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji.

Atẹjade ti akọwe Gomina ipinlẹ naa, Abbar Anwar fi sita laipẹ yi lo fidi iroyin naa mulẹ, to si ni ẹgbẹrun lọna ogun (20,000) nijọba yoo fawọn iyawo ti wọn gbe gẹgẹ bi owo ori wọn.

AWIKONKO gbọ pe ọgbọn miliọnu nijọba Kano ya sọtọ fun eto naa, ti wọn si lawọn nnkan bi bẹẹdi, gilaasi, foomu atawọn nnkan inu ile ni wọn yoo tun fowo naa ra fawon ti wọn ṣeyawo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI