Ti ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ kii tan leekana lọrọ
igbẹjọ idibo gomina ipinlẹ Oṣun da fawọn oludije ẹgbẹ osẹlu PDP Ademola
Adeleke, lẹyin ti aburo rẹ Dele sọ pe Adeleleke yoo bori nile-ẹjọ to gaju lọ.
Ẹ o ranti wi pe ile ẹjọ kotẹmilọrun l'Abuja da idajọ
igbimọ igbẹjọ idibo gomina ipinlẹ Oṣun to waye lọdun 2018 to sọ pe Adeleke lo
jawe olubori ninu ibo ọhun nu ti o si ni Gomina Gboyega Oyetola lo wọ le.
Ṣugbọn Dele ni o da oun loju t'ada pe ile ẹjọ to ga
julọ naa yoo da idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun nu.
Adeleke kọkọ bori pẹlu ibo 254,698 ti Gomina Oyetola
to jẹ oludije fẹgẹ APC si ni 254,345 ninu idibo to waye lọjọ kejilelogun oṣu
Kẹsan-an ọdun 2018.
Ṣugbọn Oyetola la Adeleke mọ lẹ lẹyin ti afikun
idibo waye lawọn ibudo idibo kan ti wọn wọgile ibo.
Dele ṣalaye pe idajọ erefee ni ile ẹjọ kotẹmilọrun
da, ati pe ile ẹjọ naa ko foju sunnunkun wo ẹjọ ọhun ki o to dajọ.
O fikun ọrọ rẹ pe gbogbo eeyan nipinlẹ Oṣun lo mọ pe
Adeleke lo wọ le ibo gomina nipinlẹ Oṣun.
- BBC
No comments:
Post a Comment