Ọnọrebu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan
lẹkun Ọbọkun/Oriade lati ṣoju niluu Abuja, Dọkita Ọlaṣiji Ọlamiju ti gbe oṣuba
kare fun ile ẹjọ kotẹmilẹrun latari igbesẹ to gbe lori idajọ idibo ipinlẹ Ọṣun
to waye lọdun to kọja.
Ana nile ẹjọ Kotẹmilọrun to
fikalẹ siluu Abuja fidi ẹ mulẹ pe Gomina Gboyega Oyetọla lo jawe olubori ninu
idib to waye lọjọ kejilelogun ati atundi ibo lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan an
ọdun to kọja.
Ninu atẹjade ti Ọnọrebu Ọlamiju
tọpọ awọn araalu tun mọ si AKOL gbe jade, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti
jẹ ko di mimọ pe ifẹ awọn araalu ni Gomina Oyetọla, to si jẹ idi pataki ti wọn
fi jade dibo fun lọpọ yanturu.
Atẹjade naa lo ka bayii pe “Nigba
ti mo n gba ẹnu awọn eeyan rere ti agbegbe Ọbọkun ati Oriade sọrọ, Mo ki gbogbo
ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ku oriire ati Ọlọlajulọ, Gomina Gboyega Oyetọla fun bo ṣe
bori nile ẹjọ kotẹmilọrun, eyi to fidi ẹ mulẹ pe ogunlọgọ awọn araalu lo jade
dibo fun un layọ ati alaafia, lai si wahala kankan.
“Idajọ to ti ile ẹjọ
kọtẹmilọrun gbe kalẹ niluu Abuja fidi ẹ mulẹ pe Gomina Gboyega Oyetọla lo jawe
olubori, eyi to fi fidi alatako ẹ, Sẹnetọ Ademọla Adeleke janlẹ. Idajọ naa lo
fi apẹẹrẹ rere ti oṣelu awaarawa lele.
“...Ki awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun di
ori wọn mu ṣinṣin, ki wọn si wa ninu igboya pe wọn dibo fun iṣejọba awaarawa
toootọ ati ijọba rere. Wọn ti fi ifẹ ati agbara wọn han. Eyi ti ko ni i jẹ ki
idibo magomago waye, to si jẹ ki ibo wọn ni onka. Iṣakoso ipinlẹ Ọṣun yoo ri i
daju pe gbogbo awọn ileri asiko ipolongo ibo ni yoo wa si imuṣẹ fun ilọsiwaju
ati idagbasoke awọn eeyan wa.”
No comments:
Post a Comment