Ta a si ṣeleri pe a maa mu ẹkunrẹrẹ rẹ wa fun un yin, ni bayii, AWIKONKO ti ri lẹta ifiposilẹ naa gba, eyi to sọ pataki idi ti Baba naa ṣe kọwe fipo silẹ lọjọ Tuside ana.
Lẹta naa ka bayii pe "Lakọkọ naa, mo fẹẹ fi
tọkan-tọkan dupẹ lọwọ yin fun anfaani ti ẹ fun mi lati sin ipinlẹ yi labẹ ijọba
yin paapaa ni saa iṣakoso ẹlẹẹkeji yin gẹgẹ bi Gomina. Mo fẹẹ fi da a yin loju
pe anfaani ti ko wọpọ lo jẹ fun mi, ati pe titi aye ni maa fi maa dupẹ.
"Sibẹ, o dun mi de isalẹ
ọkan mi pe mo fun ọga ti mo fẹran ju niwe ifiposilẹ.
"Nipa iṣẹ ti a gbe lemi
lọwọ, Mo ṣoju awọn eeyan mi nilẹ Awori, ijọba ibilẹ mi ati ipinlẹ Ogun lalapọ,
ko si nnkan ti mo le ṣe ju pe ki n pada sile lọọ bawọn eeyan atawọn ẹbi mi pẹlu
ibalẹ ọkan.
"Awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ
laipẹ jẹ ki n gbagbọ pe awọn ipinu yi le ma jẹ ki otitọ farahan bi mo ba
tẹsiwaju lati maa di ipo yi mu gẹgẹ bi Kọmiṣana fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.
Ohun ti yoo tẹyin ẹ yọ ni pe maa di ajoji niwaju awọn eeyan.
"Pẹlu ọjọ ori mi, mi o le
gba a.
"Ọga mi, gẹgẹ bi ibi ti mo
ti n bọ bi oṣiṣẹ ijọba, ẹkọ ti mo ri gba ni pe ki n maa gbọnran, ki n si ni
itẹriba si ọga mi, ṣugbọn pẹlu aṣẹ ti ẹ gbe kalẹ laipẹ yi lori ọrọ Ọba lawọn
agbegbe kan niluu Ọta tako ẹri ọkan mi pupọ, ati ifẹ ọkan awọn eeyan mi ti mo n
ṣoju.
"Lẹẹkan si, ẹ ṣi n jẹ ọga
mi nidi oṣelu ati ẹgbọn mi. Mo dupẹ lọwọ yin fun ọwọ, ifẹ ati anfaani ti ẹ fun
mi lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan rere nipinlẹ Ogun."
Ọpọ awọn to gbọ nipa nnkan to ṣẹlẹ yi lọrọ naa ṣi n ya lẹnu titi dasiko yi.
No comments:
Post a Comment