Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu
ibẹrubojo ni ọkan lara awọn Sẹnetọ orileede yi, Sẹnetọ Buruji Kaṣamu wa, latari
bi ile ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Eko ṣe paṣẹ pe ki wọn wu ẹjọ ẹ jade pata lọjọ kẹfa oṣu kẹfa ọdun yi.
Sẹnetọ Kaṣamu lo n ṣoju ẹkun Ogun East nile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria, naa ti wa a pe ẹjọ ti ẹ lati tako aṣẹ naa, eyi ti wọn pe nọmba ẹ ni
FHC/L/CS/930/2018.
Lara awọn to fọrọ ẹjọ naa to leti bayii ni Ọga ọlọpaa patapata lorileede Naijiria, Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Alakoso eto aabo, ajọ to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA ati ọga ologun orileede yi.
A gbọ pe Kaṣamu ti rawọ ẹbẹ pe ki wọn ma ṣe gbe oun nibikibi to ba wa lati foun pamọ di asiko ti yoo foju bale ẹjọ naa. Bẹẹ lo tun n rawọ ẹbẹ pe ki wọn fi oun lọkan balẹ lati rin bo ba ṣe wu oun laarin ilu.
No comments:
Post a Comment