Adura nnla-nla lawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun kaakiri n fi ranṣẹ si Gomina Ibikunle Amosun lori bo ṣe fitan tuntun balẹ kaakiri ipinlẹ naa, pẹlu awọn akanṣẹ iṣẹ oriṣiriṣi to ṣe lasiko ijọba ẹ, eyi ti yoo pari lọjọ Wẹside ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un.
Ṣaṣa niluu ti Gomina Amosun ko ṣiṣẹ de laarin ọdun mẹjọ ẹ, to si jẹ pe onii ti i ṣe ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun ni Aarẹ Muhammadu Buari kọwọ rin in pẹlu awọn isọngbe ẹ lati ṣi awọn iṣẹ akanṣe naa kaakiri.
Ẹ gbe oṣuba fun Gomina Amosun o, Ogidi Ọmọ-ọkọ ni.
No comments:
Post a Comment