Bo ṣe ku ọjọ bii marun-un ki
saa iṣakoso Gomina Abiọla Ajimọbi tiinlẹ Ọyọ pari, Gomina naa ti bu ọwọ lu
olori awọn oṣiṣẹ tuntun nipinlẹ naa, Arabinrin Ọlọlade Agboọla.
Ni kete ti olori awọn oṣiṣẹ
ipinlẹ naa tẹlẹ, Arabinrin Hannah Ogunẹsan fẹyinti ni ijọba yan Arabinrin
Agboọla pe ko gba ipo lọwọ ẹ, ki iṣẹ ma ba a duro nipinlẹ naa.
Ọjọ Fraide ana ni eto naa waye
nile-iṣẹ ijọba to wa lagbegbe Agodi, Ibadan.
Ọmọ bibi ilu Ibadan ni
Arabinrin Agboọla, oun ni iyawo Ọnọrebu Hosea Agboọla tawọn eeyan mọ si
Hallelujah.
Bakan naa ni obinrin naa tun jẹ
akọwe agba l’ẹka to n ri sọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya (Permanent Secretary,
Ministry of Youth and Sports).
No comments:
Post a Comment