GBENGA ṢA IYA Ẹ PA L'AKURẸ, LOUN NAA BA POKUNSO N'IKARẸ-AKOKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 6, 2019

GBENGA ṢA IYA Ẹ PA L'AKURẸ, LOUN NAA BA POKUNSO N'IKARẸ-AKOKO

Gbogbo adugbo kan ti wọn pe ni Oyinmọ Quarters, lagbegbe Ikarẹ-Akoko, ipinlẹ Ondo lo fẹẹ le daru lọjọ Aiku Sande ana, nigba ti gendekunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ayọtunde Gbenga Ọpẹyẹmi pokunso laarin oru, nitori to n gbọ finrinfinrin pe awọn ọlọpaa n bọ wa a muu.

Ohun ta a gbọ ni pe ṣe ni Gbenga ṣa iya ẹ, Arabinrin Ajimọ, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57) pa, to si sa kuro nibẹ lo n gbe lọdọ Iyaagba ẹ.

A gbọ pe Ikarẹ-Akoko ni Ajimọ n gbe tẹlẹ, nibi to bimọ mẹta sii, to si kuro nibẹ lọọ fẹ ọkọ min in siluu Akurẹ, nibi to ti pada bimọ meji bayii.

Ọrọ kan ni wọn loo ṣẹlẹ laarin Gbenga ati Mama ẹ, to si ki ada mọle ṣaa pa. Kaṣiri ẹ ma ba a tu lo mu ko salọ pada sọdọ iyaagba ẹ toun n gbe n'Ikarẹ-Akoko.

Awọn araale Mama ẹ yi ni wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si tọpinpin ẹ de ibi to wa, bo ṣe gbọ pe awọn ọlọpaa ti n wa oun lo ba dide laarin oru, to si lọọ pokunso sẹyinkule ile naa.

Ọkan lara awọn ara ile naa toun jade sita lati ṣẹyọ (urinate) lo deede ri oku Gbenga nibi to so ara rẹ kọ si, ko too pariwo sita fawọn araadugbo lati wa a wo nnkan iyalẹnu toun ri.

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn pada lọọ gbe oku naa kuro, ta a si gbọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ dasiko yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI