GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ FẸẸ KO IWE TUNTUN MEJI JADE LỌSẸ YI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 12, 2019

GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ FẸẸ KO IWE TUNTUN MEJI JADE LỌSẸ YI

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo eto lo ti pari patapata fun ti ayẹyẹ ikojade awọn arambara iwe meji to nii ṣe pẹlu dida okoowo silẹ lọwọ ara ẹni, eyi ti gbajumọ sọrọsọrọ tawọn eeyan n wo gẹgẹ bi awokọṣe, Ọgbẹni Adeyinka Adegbitẹ fẹẹ ko jade.

Ọjọ Wẹside ọsẹ yi gan an ni ayẹyẹ naa yoo waye ni gbọngan awọn oniroyin to wa ni Oke-Ilweo niluu Abẹokuta, bẹrẹ lati aago mejila ọsan.

Awọn iwe naa lo pe ni “40 Businesses You Can Do In Nigeria With Little Or No Cash” ati magasinni to n ṣafihan ipolowo ọja, iyẹn Benchmark Magazine.

Odu ni Adeyinka Adegbitẹ, tọpọ mọ si ‘Ojulowo Ọmọ Baba Tiṣa’ lagboole sọrọsọrọ, awọn ẹwa ede ati aṣa to n lo lori redio lo jẹ kawọn eeyan maa gba tiẹ gidi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI