Asisat Oshola, Desire
Oparanozie ati Onome Ebi jẹ pataki lara ikọ ẹlẹnimẹtalelogun ti yoo ṣoju ẹgbẹ
agbabọọlu obinrin ti Naijiria, Super Falcons ni France.
Idije naa ni yoo jẹ ti aṣekagba
idije ife agbaye awọn obinrin l'orilẹ-ede France.
Oludari eto ibanisọrọ nileeṣẹ
ajọ to n mojuto ere idaraya ni Naijiria, NFF, Ademọla Ọlajire ninu ikede kan to
fi sita l'alẹ ọjọ Ẹti sọ pe orilẹ-ede Austria nibi ti Super Falcons wa lọwọlọwọ
fun igbaradi ni olórí akọnimọọgba wọn, Thomas Dennerby ti kede orukọ naa.
Awọn mi i ti orukọ wọn tun wa
ninu ikọ naa ni Tochukwu Oluehi, Chiamaka Nnadozie, Alaba Jonathan, Osinachi
Ohale, Faith Michael, Chidinma Okeke, Rita Chikwelu, Ngozi Okobi-Okeoghene,
Halimatu Ayinde, Ogonna Chukwudi.
Bakan naa ni Evelyn Nwabuoku,
Amarachi Okoronkwo, Uchenna Kanu, Fransisca Ordega, Uchenna Chinaza, Anam Imo,
Rasheedat Ajibade ati Chiwendu Ihezuo yoo kopa.
Ọjọ Kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2019
ni Super Falcons yoo gbera kuro ni Austia lọ si orilẹ-ede France ti idije naa
yoo ti waye.
Wọn yoo si koju Norway, Korea
ati France ni ipele akọkọ.
- BBC
- BBC
No comments:
Post a Comment