Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ
Ogun, ti wọn
yoo si ṣe ibura fun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, Ọmọba Dapọ Abiọdun, tun ti mu da awọn
oṣiṣẹ nipinlẹ naa loju pe gbogbo ileri toun ṣe
pẹlu wọn lakooko ipolongo oun loun yoo mu ṣẹ fun wọn, boun ba depo.
O sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Wẹside ana, eyi to fi ki awọn
oṣiṣẹ ku ayajọ wọn ti wọn ṣe loni in, nibẹ lo ti ṣajọyọ pẹlu wọn.
Atẹjade naa lo ka bayi pe “Mo bawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣajọyọ ayajọ ti wọn n ṣe loni-in, inu mi dun pe ayẹyẹ
ti wọn
ṣe
lọdun
yii jẹ
nnkan ayọ
ati ipadabọ
sijọba
ti yoo bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii”.
“Ki ẹ Ie mọ pe mi o gbagbe,
mo fẹẹ muu wa si iranti yin lara awọn
ileri ti mo ṣe
lakooko ipolongo lati le mu igbe aye dẹrun fawọn oṣiṣẹ, ki ẹ le mọ pe mo fi yin sọkan.
Idasilẹ ileeṣẹ ti yoo maa ri bawọn
oṣiṣẹ yoo ṣe maa ṣe daadaa ati imu-ayedẹrun
fun wọn.
Gbigba awọn olukọ siṣẹ lọna ti yoo dọgba pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba.
Ṣiṣe atunṣe lori awọn oṣiṣẹ fẹyinti ati idasilẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti tipinlẹ ati lawọn ijọba ibilẹ atawọn nnkan mii in ta jọ
so papọ.
Bakan naa lo tun fikun ọrọ ẹ pe gbogbo ọna lawọn yoo tun gba lati rii pe awọn
ṣamulo
ofin to gbe igbimọ
laarin awọn
oṣiṣẹ ati aṣoju awọn oṣiṣẹ lati ṣiṣẹ lori awọn owo ajẹmọnu ti wọn jẹ awọn oṣiṣẹ.
O ni ọsẹ akọkọ ti wọn ba gbakoso ni wọn
yoo ṣagbekalẹ
igbimọ
naa.
Dapọ Abiọdun tun sọ pe awọn yoo rii pe awọn
oṣiṣẹ nu awọn aṣoju rere ninu ijọba
oun eyi ti yoo jẹ
ki irẹpọ
tun wa laarin wọn.
O wa rọ awọn oṣiṣẹ ki wọn lo akoko yii lati ṣatilẹyin fawọn tijọba tuntun ba.
No comments:
Post a Comment