Bi wọn ba n sọ nipa awọn ileeṣẹ
to n ta ẹru awọn ọmọde, bẹrẹ lati ọmọ oojọ, odu ni ileeṣẹ TUSNAH NIGERIA ENTERPRISES kii ṣaimọ
foloko niluu Abẹokuta ati agbegbe ẹ, ko da, ọpọ awọn ti wọn ti de ileeṣẹ naa to
wa lagbegbe Imọ, ati eyi to wa ninu ọja Lafẹnwa ni wọn n ki aje ku ikalẹ pẹlu
bo ṣe jẹ pe ko si oniruuru ẹru to fi mọ ounjẹ ọmọ ti ẹ wa debẹ, ti ko si.
Yatọ sawọn nnkan eelo ati ounjẹ
ọmọ, oriṣiriṣi ohun iṣere awọn ọmọde, to fi mọ eyi ti wọn nlo, bi wọn ba ṣẹṣẹ
bẹrẹ sii rin lo pe perepere sibẹ.
'Gan-an ni a fi ji', iroyin ko
to afojuba lo n jẹ bẹẹ, ati pe owo ti won n ta ọja wọn ko gani lara rara bii
tawọn ọlọja min in, ere ajẹpajude kii ṣe ti wọn.
Aṣọ, abọ ounjẹ, fida, ike omi, fila, bẹẹdi, aṣọ inudi, pampaasi, ifọyin ati bẹẹbẹẹlọ lo wa nileeṣẹ wọn.
Aṣọ, abọ ounjẹ, fida, ike omi, fila, bẹẹdi, aṣọ inudi, pampaasi, ifọyin ati bẹẹbẹẹlọ lo wa nileeṣẹ wọn.
Ohun to yẹ ki ẹ mọ ni pe lati
oke-okun, iyẹn ilu Oyinbo ni wọn ti ra awọn ọja ti wọn, bẹẹ lawọn ileeṣẹ to n
ṣe awọn ẹru ati ounjẹ ọmọ lorileede Naijiria ko le fi ileeṣẹ TUSNAH ṣere ti wọn
n gbe ọja wa fun wọn lati ta, eyi ni pe awọn ọja ti wọn n ta kii ṣe atọwọdọwọ
rara.
Pabambari ẹ ni pe, ki i ṣe
dandan ki ẹ gbe owo dani bi ẹ ba fẹẹ ra ọja nibẹ, ẹrọ to n fowo ranse loju ẹsẹ,
iyẹn POS Machine wa nibẹ ni sẹpẹ, bẹẹ laaye tun wa fun yin lati fi owo ranṣẹ
lati ori foonu yin, gẹgẹ bi asiko aye to lu jara ti a wa yi.
A ti ẹ tun gbọ pe bi ẹ ba pe wọn
lori aago, ti ẹ ṣalaye eyikeyi ọja ti ẹ ba fẹẹ ra, wọn yoo ba a yin gbe e wa
sile yin lowo ti ko gani lara rara.
Ọrọ ọlọrọ kii saba a dun lẹnu
ti wa, ko ma ba a dabi ipolowo, ẹyin naa, e dide bayii, ẹ lọ fun oju yin
lounjẹ, ti ẹ ko si ni i kabamọ pe ẹ ba wọn dowo pọ.
Fun alaye lẹkunrẹrẹ, awọn nọmba
yi ni ki ẹ pe: 07036217439, 07085086416, 08029322644.
No comments:
Post a Comment