EKOO NI GBENGA ATI KOREDE TI FIBỌN GBA MỌTO, IDIROKO LỌWỌ TI TẸ WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 27, 2019

EKOO NI GBENGA ATI KOREDE TI FIBỌN GBA MỌTO, IDIROKO LỌWỌ TI TẸ WỌN

Ni nnkan bi aago marun un aarọ onii, Monde lọwọ awọn Fijilante ti a mọ si SO SAFE labẹ ọga wọn, Soji Ganzallo tẹ awọn adigunjale meji kan ti wọn sọ pe mọto nikan ni wọn n fibon gba kaakiri orilẹ-ede Naijiria, Gbenga Ojo ati Ọlakunle Korede.

Orilẹ-ede Bẹnin la gbọ pe wọn n ta gbogbo awọn mọto ti wọn ba ji gbe, tabi fibọn gba naa si.

Nigba taṣiri maa tu, wọn ni asiko tawọn eeyan naa n gbe mọto Toyota Corolla ti nọmba idanimọ ẹ jẹ AKD 465 FQ ni wọn fẹ lọọ ta danu si Cotonou, ko too di pe ọwọ tẹ wọn lagbegbe Idiroko.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbenusọ fun ileeṣẹ SO SAFE, Ọgbẹni Kọlawọle Mọruf jẹ ko di mimọ pe Ọgbẹni kan ti pe ni Olumoye Fẹmi to n gbe ni Alapẹrẹ, Ketu nipinlẹ Ekoo ni wọn fibọn gba mọto naa lọwọ laipẹ yii, ati pe awọn i fa awọn ọdaran naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju awọn iwadi to ba ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI