EFCC NI KI SARAKI MAA GBARADI LATI KAWỌ-PỌYIN ROJỌ, LO BA NI IPADE ỌTẸ LASAN NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 12, 2019

EFCC NI KI SARAKI MAA GBARADI LATI KAWỌ-PỌYIN ROJỌ, LO BA NI IPADE ỌTẸ LASAN NI

"Imọkimọ ko ma gbọdọ jọ, etekete ko le duro o, ẹnikẹni to ba di ẹru ọran ni yoo fori ara rẹ gbe, tori Oluwa lemi ba duro", wọnyi ni orin ti olori ile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria, Senetọ Bukọla Saraki n kọ lasiko yi.

To tun n tẹnu mọ ọrọ kan ṣoṣo pe ipade ọtẹ lasan ni wọn n di mọ oun.

Laipẹ yi ni ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorileede Naijiria kọ lẹta si Bukọla Saraki pe ko maa gbaradi lati yọju sawọn lati wa a ṣalaye awọn owo oṣu to gba lasiko to fi jẹ Gomina ipinlẹ Kwara ati owo oṣu to gba gẹgẹ bi olori ile igbimọ aṣofin agba.

Ninu lẹta naa ni ajọ EFCC ti jẹ ye Bukọla Saraki pe ko ni ohunkohun lati bẹru ti ko ba ti hu iwa ibajẹ, to si da a loju pe ọkan oun mọ bi ẹgbọn owu.

Ọgbẹni Tony Orilade to jẹ adari eto iroyin fun ajọ naa, ninu atẹjade to fi sita sọ pe ajọ naa n ṣewadii gbogbo owo to gba gẹgẹ bi owo osu lasiko to jẹ gomina ni ipinlẹ Kwara ati eyi to gba lasiko to jẹ aarẹ Ile Igbimọ Asofin.

Orilade ni awọn ni ẹsun iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorisirisi ti wọn fi kan Bukola Saraki, nitori naa wọn rọ ọ lati jẹ ki wọn se isẹ wọn gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ.

Ajọ EFCC ni ki Saraki ranti pe awọn ni asẹ labẹ ofin ati ibura lati ri wi pe awọn fi opin si iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria.

Nigba toun naa si n fesi si lẹta naa sọ pe ajọ EFCC kan fẹẹ ba oun lorukọ jẹ lasan ni, nitori pe ohun ko ṣẹ ẹsẹ kankan, ati pe wọn kan n ditẹ mọ oun ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI