Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọru ni wọn gbe oku arabinrin kan ati ọmọde jojolo to ṣẹṣẹ bii ni
abiku wa si ileewosan nla naa lẹyin ti wọn ku nigba ti obinrin naa n rọbi ni
ileewosan awọn ọlọpaa to wa ni ilu Akurẹ kan naa.
Amọṣa ọrọ di womi-n-wo ọ nigba
ti awọn ẹbi Arabinrin naa de ile igbokupamọsi ileewosan nla Ondo state
specialist Hospital nilu Akurẹ ni ọjọ Abamẹta lati gbe oku oun ati ẹjẹ ọrun ti
wọn jọ jalaisi naa.
Si iyalẹnu wọn ati ọpọ eeyan nibẹ lati rii pe oku Arabinrin naa nikan ni wọn ba, wọn ko ri oku ọmọ tuntun jojolo naa gbe.
Si iyalẹnu wọn ati ọpọ eeyan nibẹ lati rii pe oku Arabinrin naa nikan ni wọn ba, wọn ko ri oku ọmọ tuntun jojolo naa gbe.
Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe oku Arabinrin yii ati ibi ọmọ tuntun to bi ni nikan ni wọn ba, ẹnikan ko si
lee sọ ohun to gbe oku ọmọ tuntun naa kuro nile igbokupamọsi naa.
Bakan naa ni 'awọn oṣiṣẹ ile
igboku pamọsi naa ko lee sọ bi oku ọmọ tuntun naa ṣe poora.'
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ
Ondo, Fẹmi Joseph to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ to si ni awọn ọlọpaa yoo gbe awọn
oṣiṣẹ ileewosan naa ti ọrọ ọhun kan fun ifọrọwanilẹnuwo laipẹ.
Amọṣa, Fẹmi Joseph ni
titi di igba ti a fi n ko iroyin yii jọ, "wọn ko tii fi panpẹ ofin mu
ẹnikẹni lori ọrọ naa.
Bakan naa, Dokita Wahab
Adegbenro to jẹ Kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Ondo ṣalaye pe wọn ti fa ọrọ naa
le awọn ọlọpaa lọwọ.
O ni ohun ti ijọba n duro de
bayii ni 'abajade iwadii awọn ọlọpaa' lori ọrọ naa.
- BBC
No comments:
Post a Comment