Ko sẹni to gbọ bi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ṣe n sọrọ laipẹ yi, to si fẹẹ le maa sunkun pe ki wọn ma ṣe di ẹru ti ki i ṣe ti ẹ le oun lori, to si loun ko mọ
ohunkohun nipa iku ọkan lara awọn aṣoju-ṣofin nipinlẹ naa, Ọnọrebu Temitọpẹ Ọlatoye ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si
Ṣugar.
Ni ọjọ idibo sipo gomina ni awọn agbenipa kan yinbọn
pa Ọnọrebu Temitọpẹ Akintoye.
Lasiko eto isinku rẹ to waye ni gbọngan awọn
lọbalọba niluu Ibadan ni ẹgbọn aṣofin naa Ọlajide Ọlatoye ti paroko ikilọ ranṣẹ
si Gomina Ajimọbi pe ko jawọ igbesẹ to ni o n gbe lati tu awọn afunrasi ti wọn
mu fun iku ẹgbọn rẹ silẹ.
O fi ẹsun kan an wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n
"Ṣehin-sọhun" laarin mọlẹbi oloogbe ati awọn apanilẹkun jaye naa.
Ọlajide
fi kun ọrọ rẹ wi pe ohun ti o tọ ni ki ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ile igbimọ aṣofin
ipinlẹ Ọyọ jawọ ninu abosi, " bi wọn ko ba fẹ fi ọwọ ara wọn gbe ọmọ
sin."
Amọṣa, Gomina Ajimọbi ni ko si otits ninu ọrọ naa
ati pe ko si idi fun oun lati wa iku oloogbe naa tabi gbiyanju ati da apaadi bo
ina eto idajọ lori iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan to fi ran amugblẹgbẹ fun un lori
eto ibanisọrọ, Bọlaji Tunji ni Gomina Ajimọbi ti ṣalaye eyi.
Ajimọbi ni ileri oun lati rii pe awọn to pa 'ṣugar'
foju ba ina ofin, ileri naa ko si tii yẹ rara.
Ki o to ku, oloogbe Temitọpẹ Ọlatoye lo n ṣoju fun
ẹkun idibo apapọ Lagelu/Akinyẹle ni ipinlẹ Ọyọ
No comments:
Post a Comment