Bọọsi nla tuntun ọlọyẹ lo fi ta
igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Ọlakunle Oluọmọ lọrẹ, eyi
to fi dipo ọkan lara awọn bọọsi nla marun tawọn tọọgi dana sun ni nnkan bi ọsẹ
meloo kan sẹyin.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ
daadaa nijọba ibilẹ Ifọ, wọn yoo mọ pe bọọsi nla marun ọtọọtọ ni Ọnọrebu Oluọmọ
ra lati maa fi gbe awọn akẹkọọ lọ sileewe wọn laarọ, ti bọọsi naa yoo tun pada
lọọ ko wọn bi wọn ba jade ileewe lọsan.
Awọn bọọsi yi la gbọ pe awọn
tọọgi tinu n bi dana sun kọja titunṣe lairo iye owo tawọn bọọsi naa je.
Ninu atẹjade ti igbakeji olori
ile igbimọ aṣofin naa, Ọnọrebu Oluọmọ fi sita fawọn oniroyin lọjọ Satide ana lo
ti gbe oṣuba kare fun gomina tuntun naa pẹlu igbesẹ naa, nitori pe ẹbun bọọsi
tuntun naa ti da ẹrin pa ẹẹkẹ awọn akẹkọọ.
Ninu atẹjade naa lo tun ti dupẹ
lọwọ gbogbo awọn to ba a kẹdun lọjọ kẹtalelogun oṣu to kọja ti wahala nla naa
ṣẹlẹ, to si tun sọrọ pẹlu igbagbọ pe awọn bọọsi min in tun ṣi n bọ lọna, eyi ti
yoo si mu irọrun de ba ikẹkọọ awọn akẹkọọ.
No comments:
Post a Comment