BI WỌN KO BA YỌWỌ BURUJI KAṢAMU L’AWO, IJAKULẸ NI YOO JẸ FUN PDP IPINLẸ OGUN LỌDUN 2023 – SẸMIU ṢOBAYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 20, 2019

BI WỌN KO BA YỌWỌ BURUJI KAṢAMU L’AWO, IJAKULẸ NI YOO JẸ FUN PDP IPINLẸ OGUN LỌDUN 2023 – SẸMIU ṢOBAYỌ

Ọkan pataki lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Alaaji Sẹmiu Ṣobayọ ti ke gbajare sawọn oloye ẹgbẹ naa lapapọ niluu Abuja pe bi wọn ba ṣi n faaye gba Sẹnetọ Buruji Kaṣamu lati di ipo gidi mu ninu ẹgbẹ naa, ijakulẹ ayeraye ni yoo maa de ba ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, ti wọn ko si tun ni rọwọ mu lọdun 2023.

Alaaji Sẹmiu Ṣobayọ lo sọrọ naa lọjọ Tọside ọsẹ to kọja yi niluu Abẹokuta nibi eto kan tawọn n fẹ ayipada rere ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, eyi ti wọn pe ni Ogun PDP Rebirth ṣagbatẹru ẹ ninu gbọngan awọn oniroyin, Oke-Ilewo.

O sọ pe nnkan pataki lo mu tun pada mu aṣeyọri ba ẹgbẹ naa ni pe kawọn pawọpọ gbe ẹgbẹ naa ga, kawọn si yọ ẹlẹyamẹya kuro laarin ara wọn, nitori pe bi ẹgbẹ naa ṣe pin si meji lo ṣakoba fun bi ẹgbẹ naa ṣe padanu ninu idibo to kọja lọ.

Ninu ọrọ rẹ diẹ lo ti sọ pe “Ẹgbẹ PDP yoo ṣi tun maa padanu ibo, iyẹn bi awọn adari wa niluu Abuja ba ṣi n gba Ọmọba Buruji Kaṣamu laaye ninu ẹgbẹ yi, ati pe ijakulẹ lo n jẹ fun wa ninu ẹgbẹ yi.”

Ṣaaju asiko yi ni ọlọri awọn ọdọ fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, Aṣiwaju Adekọla Adeoye gbawọn adaari ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun lamọnran pe ki wọnyago fawọn iwa to n ba ẹgbẹ jẹ, to si le pa ẹgbẹ run patapata, dipo bẹẹ, ki wọn fi ifẹ ba ara wọn lo pọ nitori pe eyi gan an lo le mu wọn ṣe aṣeyọri.

Aṣiwaju Adeoye je kọ di mimọ pe iṣọkan to wa ninu ẹgbẹ naa lo ṣokufa aṣeyọri fun Ṣeyi Makinde ninu idibo to kọja, bawọn naa ba si faaye gba iṣọkan ati alaafia laay, dandan ni ki wọn rọwọ mu ninu idibo ọdun 202.

O fi ye wọn pe bi ko ba si iṣọkan, iduro-ṣinṣin ati ifẹ to jọba ninu ẹgbẹ oṣelu naa, ati paapaa awọn aṣiṣe ati ijọba radarada ti Gomina Abiọla Ajimọbi ṣe, PDP le ma ri anfaani naa jẹ lati gba ijọba lọjọ kẹsan an oṣu kẹta.
 
Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe irin ajo ọdun 2023 ti bẹrẹ latigba ti wọn ba ti bura fun ijọba tuntun yi, ki wọn si bẹrẹ igbesẹ lati yanju aawọ to wa laarin wọn.

Kọmureedi Niyi Ọṣọba gbe oriyin fawọn to ṣagbatẹru eto naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati wa iṣọkan ninu ẹgbẹ naa, ati paapaa iṣọkan ni yoo jẹ atẹgun fun aṣeyọri ninu irin ajo ọdun 2023.

Ninu ọrọ ti ẹ ṣaaju asiko yi ni ẹni to ṣagbatẹru eto naa, ọjọgbọn nidi iṣẹ iroyin ati igbohunṣafẹfẹ, Arabinrin ọmọlara Popoọla fidi ẹ mulẹ pe pataki idi toun fi gbe eto naa kalẹ ni lati jẹ kawọn agbaagba ẹgbẹ naa parapọ, ki wọn si gbe PDP dide lọdun 2023, tori pe oun nikan lawọn araalu n fẹ.

Lara awọn to tun wa nibi eto naa ni: Kọmureedi Temitọpẹ Ṣofẹla, Oloye Arabinrin Ọjẹlabi, Ọnọrebu Iṣọla Ibrahim,  Oluwafẹmi Victor, Ọnọrebu Ṣina Popoọla, Ọnọrebu Ṣọla Ọlọmọla lati Ondo, Ọnọrebu Arabinrin Abiọdun Oyefusi, Ọnọrebu Dele Ajiṣebutu atawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI