Bi wọn ba n ka awọn oṣere tiata taye n gba ti wọn lasiko yi, paapaa awọn oṣerebinrin ti wọn ṣẹṣẹ n dide nidi iṣẹ naa, ko si bi wọn ṣe maa darukọ mẹwaa ninu wọn, ti wọn ko ni i darukọ Adeṣinaọla Ọlabisi Adufẹ nitori pe odu ni, ki i ṣaimọ foloko.
Ki i ṣe pe tori Adufẹ rẹwa pupọ lobinrin ni wọn ṣe maa ka a mọ awọn mẹwaa akọkọ, bi ko ṣe pe ọgbọn, ọpọlọ, agbekalẹ, atawọn ipa manigbagbe to n ko nidi iṣẹ naa, paapaa bo tun ṣe n fi gbogbo ara ṣiṣẹ naa.
O fẹ ẹ le jẹ pe ninu fiimu marun un, ṣaṣa ni ki ẹ ma ba Ọlabisi Adufẹ ninu meji bi ko ba jẹ mẹta.
Laipẹ yi ni Obinrin naa b'AWIKONKO sọrọ, to si sọ bo ṣe bẹrẹ iṣe tiata lọdọ Iyabọ Ojo, atawọn ipenija to ba pade nidi iṣẹ naa. Bẹẹ lo sọrọ lori awọn oṣerebinrin ti wọn n gbe igbe ayederu. Ẹ ka ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ naa:
Orukọ mi
Orukọ mi ni Adeṣhinaọla Ọlabisi Adufẹ
Bi mo ṣe bẹrẹ iṣẹ tiata
Ọdun 2005 ni mo bẹrẹ iṣẹ tiata ni pẹrẹu, bo
tilẹ jẹ pe mo n ṣe tẹlẹ, mi o kan fi gbogbo ara sii ni. Ṣugbọn nigba to ya, mo bẹrẹ si i nifẹ si i latari awọn nnkan ti mo n ri nidi ẹ, ti mo si tun ri i pe mo lẹbun ẹ. Ọdọ ọga mi, Iyabọ Ojo ni mo ti
bẹrẹ iṣẹ tiata. Igba to pẹ diẹ, mo tun ba awọn min in ṣiṣẹ,
nitori pe ẹni to ba fẹẹ kọgbọn, to si fẹẹ ni iriri daadaa, ko gbọdọ duro soju
kan, igba ti mo rii pe o ti yẹ ki n da duro, idi ni yii ti mo fi bẹrẹ iṣẹ temi naa.
Awọn obi mi fara mọ ọn
Wọn fọwọ sii nigba ti mo sọ fun wọn, nnkan pataki to jẹ awọn obi mi logun ju ni pe keeyan ka iwe de gbongbo, ko si gboye nidi iwe naa. Ileewe ṣe pataki sawọn obi mi, nitori pe wọn gbagbọ pe beeyan ba kawe, iṣẹ to ba dawọ le yoo yọri si rere.
Fiimu ti mo ti kopa
Mi o le ka iye fiimu ti mo ti kopa ninu ẹ, ṣugbọn mo ṣi le ranti diẹ,
lara wọn ni Aigbọnran tawọn bii Autin Emmanuel, Madam Shery ti kopa nibẹ; Osas Ọmọge Benin ti Mercy Aigbe ṣe; Baba No Regret; Abikẹ Alara; Jambito; Ejigbẹdẹ; Ọmọboriowo; Irọ ati bẹẹbẹẹlọ.
Adojukọ
Loootọ, oriṣiriṣi adojukọ ni mo ba pade, nitori pe ko si iṣẹ ti ko ni adojukọ laye yi. Lara awọn adojukọ ni owo, ka lọ si lokeṣan lai ri ounjẹ jẹ, ka ṣiṣẹ lai gba owo atawọn min in bẹẹ, ta a si n gbiyanju lati ba ẹgbẹ pe. Mo tun n ṣiṣẹ karakara lati le duro lẹgbẹ awọn to bẹrẹ ṣaaju mi, iyẹn awọn ọga mi ti mo pade, ti mo si n ri i pe emi naa kun
oju oṣuwọn. Nigba ti mo fẹẹ ya awọn fiimu mi kan, aimọye igba ni mo ti gbiyanju lati pe awọn to jẹ gbajumọ sidi iṣẹ
mi, ṣugbọn ti wọn ko raaye, ẹdun ọkan lo jẹ fun mi lawọn asiko yẹn.
Ololufẹ mi ki i jowu to ba n wo sinima ti mo ti n ṣere ifẹ
Ajọyepọ gbọdọ wa laarin ololufẹ meji, nigba ti mo maa bẹrẹ iṣẹ tiata, mi o ni ololufẹ kankan nigba naa, ṣugbọn nigba to ya, mo ni ololufẹ. Ololufẹ mi mọ iru iṣẹ ti mo n ṣe, o si ye e pupọ, ko si jowu rara, paapaa to ba ri mi nibi ti ọkunrin ti n tẹnu bọ mi lẹnu, nigba to jẹ pe ki i ṣe pe a n ṣe ni toootọ. Ọpọ awọn
obinrin ni wọn ko si nile ọkọ, ṣugbọn tori pe awa jẹ gbajumọ lo jẹ kaye ri
nnkan to n ṣẹlẹ si wa, ipenija ololufẹ naa tun wa fawọn kan. Afẹsọna gbọdọ ni ifarabalẹ
pẹlu iṣẹ ti iyawo ẹ ba yan laayo.
Aṣọ Iwọkuwọ
Loootọ, o pọ lasiko yi, emi gan an bi ẹ ṣe n wo mi yi, ko si aṣọ ti mi o le wọ bi mo ba ti wa niwaju kamẹra, o kan jẹ pe mi o le wọ awọn aṣọ naa nita gbangba, ṣugbọn mo le wọ wọn bi mo ba wa lori itage. Bi iṣẹ tiata ṣe ri niyẹn.
Awọn to fẹẹ ba wa
laṣepọ ka to ba wọn ṣiṣẹ
Ko sibi ti iru nnkan bẹẹ ko ti n ṣẹlẹ, bo ṣe
n ṣẹlẹ ni ṣọọṣi, lo n ṣẹlẹ ni mọṣalaṣi, to si n ṣẹlẹ kaakiri awọn ileeṣẹ ati
lagbo oṣelu, ko jẹ tuntun. O wa ku sọwọ obinrin ti wọn ba fi iru nnkan bẹẹ lọ lati fọgbọn ṣe e. Idi ti
tọdọ wa ṣe pọ ni pe awọn eeyan wa naa ti maa n gbe soju ju, nnkan to fa gan an re e. Aimọye iyawo ile to n yan ale, ti wọn ko si ṣiṣẹ tiata, bo ba ṣe wu onikaluku
lo ṣe le gbe igbe aye ẹ, ko kan aye.
Mi o le ṣere ibalopọ lailai
Gẹgẹ bi oṣere, a gbọdọ mọ awọn nnkan to rọ mọ
iṣẹ yi, ere ifẹnukonu lo wọpọ lasiko yi, ko si nnkan to buru nibẹ, kii ṣe
pe a fi n ṣe aṣẹwo, bi ilana ati ofin iṣẹ yi ṣe ri niyẹn. Ko si ipa ti mi o le ko nidi iṣẹ yi. Eyi ti
mi o le ṣe nnaa wa, Bi wọn ba ni ki n wa ṣere ibalopọ ti gbogbo aye maa wo, iyẹn blue-film, ko da a, ki wọn gbe ọgbọn miliọnu naira fun mi, mi o le ṣe e, tori pe ko si ninu aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba
wa. Ko da, bi ẹ ba gbiyanju lati gbe iru fiimu bẹẹ jade sita, ajọ to n ri sọrọ fiimu to n jade, iyẹn Censors Board gan an ko ni i faaye gba a, ko da, wọn tun le ni ki iru ẹni to fẹẹ gbe e jade lọọ san owo itanran bi ko ba ṣọra. Ki i ṣe nnkan to bojumu laarin awujọ wa.
Ipa ti mo ko, eyi ti mi o le gbagbe
Mi o le gbagbe ọjọ ti wọn ni ki n wa kopa ninu fiimu kan, wọn ni were ni mo maa ṣe, ẹru kọkọ ba mi nitori pe mi o ṣe e ri. Mo ni lati ma a ṣe igbaradi yẹn lati inu ile. Awọn ti wọn ri bi mo ṣe n ṣe e gan n wo o pe ki lo n ṣe mi. Ọlọrun ma fi were dan wa wo, ko rọrun rara. Ẹẹkeji ni wọn sọ pe ki n wa a ṣere ọlọti, ẹmi ti o mu ọti ri, bawo ni mo ṣe fẹẹ ṣe e, Ọlọrun gbakoso nigba ti mo de lokeṣan. Mi o mu ọti, ṣugbọn mo ṣ ju ọlọti gan an lọ.
Fiimu ti mo ti gbe jade funra mi
Fiimu mẹrin ni Ọlọrun ti gba ọwọ mi gbe jade,
lara wọn ni, Ẹwa Ibale ti mo gbe jade lọdun 2013; Irin Ajo Ẹda to jade lọdun 2016; Ọrọ Aje lọdun 2018; Adufẹ Mi to jade nibẹrẹ ọdun yi ati Iwa ti ko ni i pẹ ẹ jade.
Awọn to wun mi lati ba ṣe fiimu
Awọn ti mi o ti i ba ṣiṣẹ pọ, ti mo si
n foju sọna lati ba wọn ṣiṣẹ papọ, awọn bi i Mama Jọkẹ Silva ati ọkọ
wọn, Olumide, mo nifẹ wọn pupọ, Baba wa Peter Fatomilọla, atawọn
agbaagba ti wọn fẹran lati maa kopa ninu sinima oniṣẹṣe.
Wahala tawọn Makẹta
Mi o ni ipenija makẹta ri, bi makẹta
ba gba iṣẹ, dandan ni kawọn naa ri ti wọn. Ni temi o, awọn makẹta n ṣe
mi daadaa. Eeyan si gbọdọ mọ iru ẹni to n ba dowopọ.
Afojusun mi
Mo fẹ ẹ jẹ awọkọṣe rere nidi iṣẹ yi, mo fẹẹ kawọn eeyan maa ri mi kaakiri, ki wọn ma a ri ipa rere lara mi.
Ni tawọn
oṣerebinrin ti wọn n gbe igbe ayederu
Ko sibi ti igbe aye ayederu
ko si. Bi ẹ ba wo awa ọmọ Naijiria daadaa, ẹ maa ṣakiyesi pe igbe ayederu lọpọ
ninu wa n gbe. Awọn eeyan, paapaa awọn to n wo wa lori tẹlifiṣan maa n nigbagbọ
pe nigba ti a ba ti jẹ gbajumọ, o lawọn nnkan ta a gbọdọ ni, ọkan pataki lara
awọn iṣoro ta n dojuko ni yii.
Ẹlomin in ṣi maa n fẹ kawọn eeyan mọ pe oun
tobi nigba to fuyẹ, ti ko si ni nnkankan. Ẹni to ba fẹ ki wọn le oun lere lo ma
maa gbe igbe ayederu (fake life). Igbe ayederu dabi owu (thread), yoo ja sọnu to ba to
asiko, asiri a wa tu sita.
No comments:
Post a Comment