Iṣẹ eṣu ni, ẹ foju aanu wo mi" lọrọ to n jade lẹnu ọdọmọkunrin ẹmọ ọgbọn ọdun kan, Babatunde
Ọlagẹṣin ti wọn loo fibinu ṣa baba ẹ lada pa, tori ko fẹ ko lọ siluu Ekoo lọọ ṣiṣẹ owo, dipo koun maa fojuoojumọ tọrọ owo kaakiri.
Agbegbe Ijokoo nipinlẹ Ogun niṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yi.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi
sọ wipe oloogbe naa lo fa ada yọ lati fi dẹru ba ọmọ rẹ. O ni nigba ti wọn jọ
wọya ija ti wọn si n du ada mọ ara wọn lọwọ ni ada naa fa oloogbe naa nikun ya.
Oyeyemi ni Babatunde wa ni ahamọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa
to n ṣe iwadi ẹsun ipaniyan to wa ni Eleweran, Abeokuta.
Awọn aladugbo sọ wipe idi ti baba naa ko fi fẹ ki
ọmọ rẹ jade ni wipe o ni oun fẹ ki o tẹle oun lọ ṣiṣẹ kan.
Afẹsunkan naa sọ fun awọn ọlọpaa wipe oun ko mọọmọ
pa baba oun.
Awọn aladugbo ti wọn ti gbiyanju lati la ija ki ọfọ
naa to ṣẹ sọ wipe awọn gbiyanju lati gbe oloogbe naa lọ ile iwosan bi ẹjẹ ṣe n
tu lara rẹ ṣugbọn o gbẹmii mi loju ọna.
No comments:
Post a Comment