O kere tan, akọroyin
marundinlọgọrun lo padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ lọdun to kọja lẹnu, gẹgẹ bii ajọ
awọn akọroyin lagbayee (IFJ) ṣe sọ.
Iye awọn to ku ju ti ọdun 2017,
ṣugbọn ko to ti awọn ọdun ti tẹlẹ nigba ti ogun Iraq ati Syria n gbona janjan.
Iku akọroyin to pọ ju ṣẹlẹ ni
ọdun 2006 nigba ti marundinlọgọjọ ku.
Awọn iye wọnyi da lori ẹnikẹni
to n ṣiṣẹ pẹlu ile iroyin.
Iku akọroyin kan ni ọdun 2018
to ya gbogbo aye lẹnu ni ti ọmọ Saudi Arabia, Jamal Khashoggi.
Oṣu kẹwaa ọdun naa lo padanu
ẹmi rẹ nigba to lọ ileeṣẹ aṣoju orilẹede Saudi ni Turkey.
Iku akọroyin naa si mu ọpọlọpọ
ibinu wa laarin Saudi ati Turkey. Ọpọlọpọ eniyan ni agbaye si bẹnu atẹ lu.
Ni oṣu to lọ ni ilẹ Gẹẹsi,
akọroyin kan Lyra Mckee ku nigba ti jagidijagan bẹ silẹ nibi ifẹhonu han kan ni
Londonderry.
Ọmọ ẹgbẹ agbebọn kan jẹwọ pe
oun lo pa akọroyin naa.
Ibo lo buru ju fun awọn
akọroyin?
Afghanistan ṣi ni orilẹede to
buru ju fun awọn akọroyin. Mẹrindinlogun lo ku nibẹ ni ọdun to kọja.
Akọroyin mẹsan lo ku ni iṣẹlẹ
kan ṣoṣo ni Kabul, lẹyin ti wọn lọ kọ iroyin nibi ti ado oloro kan ti bu gbamu.
Wọn ko mọ wipe ẹṣin-ò-kọkú kan
to to ado oloro mọra ti darapọ mọ wọn bi pe akọroyin naa ni oun.
Ni apa ila-oorun Afghanistan,
akọroyin BBC, Ahmad Shah ku ninu awọn ikọlu to waye ni agbegbe Khost.
Bakan naa ni awọn akọroyin ku
ni orilẹede Amẹrika naa pẹlu.
Wọn yinbọn pa marun un nigba ti
awọn agbebọn ṣe ikọlu si iwe iroyin Capital Gazette ni Mariland. Arakunrin kan
to ti gbiyanju lati gbe iwe iroyin naa lọ ile ẹjọ tẹlẹ ri lo ṣe ikọlu naa.
Ajọ IFJ ni awọn ti wọn ko le
fara da awọn oun to wa ninu iroyin, pẹlu iwa jẹgudujẹra lo n fa ti awọn
akọroyin fi wa ninu ewu.
Ni ọdọọdun, ajọ to n ja fun
aabo awọn akọroyin ni agbaye maa n ya aworan awọn akọroyin to wa ni ahamọ ni
ipari ọdọọdun.
Awọn orilẹede to ni akọroyin to
pọju ni agbaye ree ni ọdun 2018:
Turkey - 68
China - 47
Egypt - 25
Saudi Arabia and Eritrea - 16
Iṣẹ iroyin ati ijọba awa-arawa
Ajọ Iṣọkan agbaye (UN) ti tan
ina soju ọrọ ipa nla ti awọn oniroyin n ko ninu ijọba awa-arawa, paapaa nigba
idibo.
Adari ajọ naa, Antonio
Guterres, sọ ninu atẹjade kan wipe ijọba awa-arawa ko le muna doko ti ko ba si
iroyin ti ko labawọn.
Courtney Radsch lati ajọ to n
ja fun aabo awọn akọroyin ni ọrọ gbigbogun ti awọn akọroyin pẹlu ọrọ ẹnu ti wa
wọpọ bayii, paapaa ni orilẹede Philippines ati Amerika.
- BBC
- BBC
No comments:
Post a Comment