Ṣe ni gbogbo awọn araalu Agbọwa
lagbegbe Ogijo, ipinlẹ Ogun gbe igba ilu ati ijo, ti wọn n kọrin yika ilu nigba
tọwọ ọlọpaa tẹ awọn ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye ti wọn tun n ji pata ka.
Awọn kan la gbọ pe wọn ta awọn
ọlọpaa lolobo pe awọn kofiri awọn ọdaran naa nibi ti wọn ti n ṣepade lọwọ, eyi
lo mu ki wọn gbera lati lọọ raga bo wọn, taṣiri wọn si tu.
Awọn ọdaran mẹta tọwọ tẹ naa ni
Ọlagboye Abidemi, ẹni ọdun mejilelọgbọn; Ọlasẹmọjọ Michael, ọmọdun mejidinlọgbọn ati Wasiu Waheed toun jẹ ọmọdun mẹtalelogun.
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ
wọn ni ọbẹ ti wọn ṣẹṣẹ fi gun eeyan tan, ada alaamu, pata obinrin ti wọn foogun
yi atawọn oogun min in loriṣiriṣi.
Gẹgẹ bi Abimbọla Oyeyẹmi ṣe
ṣalaye f’AWIKONKO, o lawọn ọdaran naa ko ni i pẹ foju bale ẹjọ latari aṣẹ
kọmiṣana wọn, Bashir Makama.
No comments:
Post a Comment