ASASI MU AYEDERU BABALAWO, LO BA FẸẸ LU KỌMIṢANA ỌLỌPAA NI JIBITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 19, 2019

ASASI MU AYEDERU BABALAWO, LO BA FẸẸ LU KỌMIṢANA ỌLỌPAA NI JIBITI

Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ baba agbalagba kan, Tayọ Ogunmọla to n fiṣẹ babalawo lu awọn eeyan ni jibiti lori foonu.

AWIKONKO gbọ pe laipẹ yi ni Tayọ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama lori foonu pe oun ṣeeṣi fi kaadi ranṣe sori foonu ẹ, ko si ba oun da kaadi naa pada tori pe babalawo loun.

A gbọ iwa yi ko ṣajeji si kọmiṣana ọlọpaa loun na ba bẹrẹ si i dibọn bi i pe oun ko mọ nnkankan. Nigba to ya ni wọn loo tun sọ fun kọmiṣana ọlọpaa pe oun ni igbakeji ọga ọlọpaa patapata lorileede Naijiria, ati pe oun le ran an lọwọ to ba ti le san iye owo kan.

Gbogbo asiko ti wọn fi n duna dura yi la gbọ pe Kọmiṣana funra rẹ ti gbe awọn ọlọpaa abẹ ẹ dide lati bẹrẹ si i tọpinpin Tayọ, ko too di pe wọn tọpinpin ẹ de agbegbe Ilogbo, nitosi Sango.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si jẹ ko ye wa pe Tayọ ti jẹwọ pe iṣẹ naa loun fi n jẹun, ati pe oun ti kọ ile nidi ẹ.

Bẹẹ lo jẹ ko ye wa pe Tayọ ti wa nibi to ti n gbatẹgun alaafia sara lọgba ẹwọn wọn, digba ti yoo foju bale ẹjọ lẹyin ti iwadii wọn ba pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI