WỌN TI BẸRẸ ITỌJU BABA SUWE L'AMẸRIKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 27, 2019

WỌN TI BẸRẸ ITỌJU BABA SUWE L'AMẸRIKA

Ni kete ti iroyin jade sita pe gbajumọ oṣere apanilẹrin nni, Alaaji Babatunde Omidina tawọn eeyan tun mọ si Baba Suwe ti tẹkọ leti lọ si Amẹrika lawọn kan ti gbe e pe o ti ku, to si mu kawọn to sunmọ ọkunrin ti wọn tun n pe ni Adimẹru naa tete tako irohin ẹlẹjẹ naa pe ko si otitọ ninu ẹ.

Ni bayii, AWIKONKO n fi asiko yi sọ fun un yin pe itọju pẹrẹu ti bẹrẹ lori aisan to n ṣe Baba Suwe ni kete to de ọsibitu ti wọn ti n tọju ẹ bayii ni Amẹrika.

Ileewosan nla kan to wa ni Rhodes Island l'Amẹrika ni wọn ti n tọju oṣere ọmọ bibi ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko naa.

Adura ti gbogbo awọn ololufe Baba Suwe n gba bayii ni pe layọ ni yoo pada waa ba awọn ni Naijiria, ti yoo si pada sẹnu tiata to sọ ọ di olokiki laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI