Adajọ ile ẹjọ
giga kan to fikalẹ siluu Calabar nipinlẹ Cross River lọjọ Mọnde ana ti sọ pe kawọn
gendekunrin mẹfa kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ẹrọ ayelujara, iyẹn
Yahoo lọ lọọ gbatẹgun oṣu mẹfa pere lọgba ẹwọn.
Awọn mẹfa
naa ni; Chigozie Bright, Kingsley Anyasor, Osinachi Samdavid, Oyasi Desmond,
Benice Anosike ati Martins Ekpemadu la gbọ pe oriṣiriṣi igba ni wọn ti lu awọn
eeyan ni jibiti lọna ọtọọtọ, to si ni ijiya labẹ ofin.
AWIKONKO gbọ
pe ẹka ileeṣẹ to n gbogun ti ṣiṣe owo kumọ-kumọ, iyẹn EFCC nipinlẹ Uyo lo rọwọ
to wọn lai pẹ yi, ti ẹri aridaju si farahan, eyi to gbe wọn dele ẹjọ.
No comments:
Post a Comment