Laipẹ yi ni awuyewuye kan jade sita pe Gomina ẹgbẹ oṣere
taita nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Owolabi Ajasa yan ọkan lara awọn gbajumọ sọrọsọrọ
tawọn eeyan n gba tiẹ lasiko yi, Ọgbẹni Ayọbami Akanji Adelani tọpọ awọn eeyan
mọ si Ọba Pedepede gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin ati bo ṣe n lọ, iyẹn Special
Assitant on Media fun ẹgbẹ oṣere TAMPAN
“Irọ ni, ahesọ lasan ni, ko le ri bẹẹ” lọrọ to n tẹnu
pupọ ninu awọn ti ọrọ naa ta si etigbọ wọn jade, ṣugbọn ti AWIKONKO wa a pada
fidi ẹ mulẹ pe otitọ pọnbele ni.
Ohun ta a gbọ ni pe ko si nnkan meji to mu ki Gomina ti
wọn dibo yan ni nnkan bi oṣu mẹfa sẹyin ninu ẹgbẹ oṣere naa, Owolabi Ajasa yan
Ọba Pedepede gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ bi ko ṣe ti ipa to ti ko lawujọ amuludun,
paapaa bo tun ṣe ṣagbatẹru ẹ lasiko ti ipolongo n lọ lọwọ, ati lẹyin idibo.
Awọn to kọkọ gbe ọrọ naa si wa leti jẹ ko ye wa pe ọpọ
igba ni Ọba Pedepede ti lo awọn nnkan ini ẹ fun aṣeyọri Kọmureedi Ajasa lati ri
i pe ipo naa ja mọ ọn lọwọ, to si pada ri bẹẹ.
AWIKONKO gbiyanju lati ba Ọba Pedepede sọrọ lati fidi
ahesọ naa mulẹ, ati pe ki lo fa a to fi jẹ pe oun ni Kọmureedi Ajasa yan fun
ẹgbẹ TAMPAN.
Iyalẹnu lo jẹ pe ohun ti Ọba Pedepede sọ ni pe lootọ ni
Gomina Ajasa yan oun gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin, ṣugbọn toun ko le sọ
pato idi ẹ, ayafi ti ẹni to yan oun ba sọ idi pataki to fi ri bẹẹ.
Lesekese ni AWIKONKO ti pe Gomina Ajasa lori foonu, ohun
to si sọ ni pe “Bẹẹni, otitọ pọnbele, ko si irọ nibẹ. Ẹ jẹ ki n mu ọrọ mi bayii
pe ẹni to ba ṣe daadaa, a fi ka sọ pe o ṣe daadaa, ka si gbe oriyin fun un.
Ayọbami Adelani Akanji, ti wọn n pe ni Ọba Pedepede jẹ amugbalẹgbẹ lori ọrọ
iroyin ninu ninu ẹgbẹ oṣere TAMPAN nipinlẹ Ogun, ki i ṣe fun emi nikan.
“Idi pataki ti mo fi yan an ni pe ki n to wọle gẹgẹ bi
Gomina ẹgbẹ oṣere TAMPAN nipinlẹ Ogun ni Adelani ti n gbaruku ti mi, to si duro
ti mi, gbogbo nnkan ti mo ba fẹ lati ọdọ ẹ lo n ṣe fun mi. Lẹyin ti mo wọle
tan, ti mo tun yan igbimọ ti yoo ṣagbatẹru ifinijoye tawọn agbaagba ẹgbẹ wa wa
a ṣe, ọpọ awọn Pedepede lo wa nibẹ lọjọ naa, bi ninu awọn ti mo yan yi ṣe jẹ
ọmọ ẹgbẹ wa naa ni wọn tun jẹ ọmọ ẹgbẹ sọrọsọrọ, Adelani nikan ni mo ri i pe o
ṣiṣẹ takuntakun.
“Ki i ṣe pe o dee de n ṣe e, o tun n lo owo apo ara ẹ
lati fi ṣiṣẹ yi. O fi ara ṣiṣẹ, o tun fi
owo ba mi ṣe. Ẹni to ba si ṣe daadaa, dandan ni ka jẹ kawọn eeyan mọ pe o ṣe
daadaa, idi ni yii to fi jẹ pe nigba ti mo daruko ẹ fun wọn, lẹsẹkẹsẹ ni wọn fi
ontẹ luu pe oun ni ka lo.”
Nigba to n sọrọ lori awọn nnkan ti wọn tun n reti lọdọ Ọgbẹni
Adelani, Ọba Pedepede bi wọn ṣe yan an yi, Gomina naa sọ pe “Mo ni igbagbọ ninu
lori awọn nnkan to ti ṣe ki n to o de bẹ ati lẹyin ti mo de bẹ pe yoo ṣe ju bẹẹ
lọ nitori pe gbogbo ọna patapata ni mo ti gba ṣe idanwo fun un, to si yege.
“Ẹni to ba fẹẹ ṣe oju aye, ko ni i mọ pe eeyan n ṣọ oun,
ẹni to ba si fẹẹ ṣe nnkan daradara, ko tun ni mọ pe eeyan n ṣọ oun, aimọye
idanwo lo ti la kọja, to si yege. O dami loju pe eeyan to n duro ti i ẹnikeji
lasiko to ba le ni Ọgbẹni Adelani.
Nigba to n gbawọn eeyan lamọnran, paapaa awọn to wa
nilana Ọba Pedepede yan laayo yi, Ọkunrin naa sọ pe “Mo sọ fun un yi lakọkọ pe
awọn ti wọn jọ jẹ Pedepede bi i marun ni
a ti ko mọra ta a si ri bi onikaluku wọn ṣe ṣe ko too di pe a yan Ọgbẹni
Adelani.
“Nnkan tonikaluku ba ṣe silẹ lo maa pada de ba, ni mo ṣe
ma a gba wọn lamọnran pe bi wọn ba pe wa fun nnkankan, ka gbiyanju lati ko ipa
ti wa. Ninu ko si aaye, leeyan gbọdọ wa aaye lati ṣe iwọnba to le ṣe kawọn
eeyan le jẹri si i.
“Emi funra mi ti mo pada di Gomina lonii, mo le sọ ọ
niwọnba pe ọpọ awọn nnkan ti mo ti ṣe sẹyin lo mu kawọn eeyan mi, paapaa awọn
ti wọn tun jẹ ọga fun gbaruku ti mi. Ki i ṣe emi nikan ni mo gbe igba apoti
Gomina, mo lawọn to ju mi lọ, mo lawọn to ti bi iru mi lọmọ ti wọn gba fọọmu,
ṣugbọn to jẹ pe emi ni wọn mu.”
Adura wa ni pe Ọlọrun yoo fun Ọba Pedepede ni oore-ọfẹ
ati agbara lati oke wa lati le lo ipo naa daadaa. Amin.
No comments:
Post a Comment