Ọmọlolu bu ẹnu atẹ lu iṣesi yii
lasiko to n ba BBC sọrọ lori bi oludije fun ipo adari Ile Igbimọ Asojusofin,
Femi Gbajabiamila ko aṣojuṣofin aadọta ti wọn sẹsẹ dibo yan lọ si Saudi Arabia
lati lọ sepade.
Iroyin gbe e jade pe adari ẹsin
musulumi ni ariwa Naijiria, Sheikh Dahiru Usman to wa pẹlu awọn aadọta
asojusofin ti wọn dibo yan naa ti buwọlu Gbajabiamila gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ
adari Ile Asojusofin lorilẹede Naijiria.
Ajafẹtọ ọmọniyan naa ni ohun to
buru jai ni ki wọn fi owo to yẹ ki wọn fi tun ilu se, lọ maa fi se ipade ti wọn
ṣi wà lori alefa. Ati wi pe o jẹ ọna ati ko owo jẹ ati lati se owo ilu
basubasu.
O fi kun un wi pe o yẹ ki Aarẹ
Buhari to n gbogun ti iwa ibajẹ kan an ni dandan wi pe, ko gbọdọ si ẹni ti yoo
lọ si oke okun lati lọ se ipade ni okeere.
Ọmololu Akinwale naa wa fi kun
wi pe ko si ipade kankan ti eniyan fẹ se ti ko le e se ni awọn ilu to lamilaaka
lorilẹede Naijiria, ti yoo si yori si rere.
No comments:
Post a Comment