Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta: Bi
iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ba fi jẹ otitọ, a
jẹ pe nnkan ko fẹẹ lo deede mọ fun Aarẹ tẹlẹri lorileede yi, Oloye Okikiọla
Oluṣẹgun Ọbasanjọ pẹlu bi wọn ṣe lo n gbe dukia ẹ ta diẹdiẹ, paapaa ti ilẹ to
fi n da oko si to wa lagbegbe Ọta, nipinlẹ Ogun.
Bo tilẹ jẹ pe lati bi ọdun to kọja si ọdun to
lọ lọhun ni Oloye Ọbasanjọ ti wọn tun n pe ni Ẹbọra Owu ti gbe ilẹ naa sita fun
awọn kan ti wọn mọ nipa ọrọ ilẹ daadaa, iyẹn Land Speculators lati maa ṣabojuto ẹ, to si jẹ pe ọkan lara awọn ọmọ ẹ naa si jẹ ọkan lara awọn to n bu ọwọ lu iwe fawọn to ba ra ilẹ naa.
AWIKONKO gbọ pe miliọnu meji ataabọ (2.5milion)
naira ni wọn n ta ẹyọ pulọọti ile kan (1plot of land), ti wọn lawọn yẹn si tun
n fun awọn to ba mu eeyan wa ra ilẹ ni ẹgbẹrun lọna irinwo (400,000) naira lori ẹyọ ilẹ pulọọti kan tẹni ti wọn ba mu wa ba ra.
Ohun ta a gbọ ni pe wọn ni ẹru kawọn ọmọ
onilẹ ma ba maa ji ilẹ naa ta lẹyin toun ba ku tan, lo jẹ ko pinu lati gbe
igbeṣe naa, ati pe ko fẹ ki ogun to ba fi silẹ lọ rare bii ti Oloogbe MKO
Abiọla.
Wọn ni nigba ti ariwo naa bẹrẹ sii kan sita,
to di pe ọpọ eeyan bere sii ko owo lọọ fi ra ilẹ naa lọpọ yanturu ni wọn ni ọkan lara awọn ọmọ Oloye Ọbasanjọ to n bu ọwọ lu iwe fawọn to ba ra ilẹ naa sọ
fun baba ẹ pe ko dawọ ilẹ tita naa duro, idi ni yi ti wọn ni Aarẹ tẹlẹri naa fi
da a duro.
Lẹyin igba die la tun gbọ pe Baba naa gbe ilẹ
to ku fun ileeṣẹ aladani kan to mọ nipa bi wọn ṣe n ta ati ra dukia, ti wọn si tun mọ nipa idagbaskoke agbegbe (developers), iyen
Fairmont Properties lati ta a fawọn eeyan, ki idagbasoke le tubọ de ba agbegbe
naa.
Ileeṣẹ Fairmont Properties yi ni wọn loo sọ
ilẹ pulọọti kan di miliọnu meje ataabọ (7.5milion) naira, ti wọn si lẹni to ba
fẹẹ kọ ile tabi dukia sori ilẹ naa lasiko yi, abẹ orukọ ileeṣẹ naa ti wọn pe ni
Fairmont Hilltop Estate ni won yoo gba ṣe e.
Bakan naa la tun gbọ pe laarin asiko ti Ọbasanjọ ati ọmọ ẹ jọ n ta ilẹ yi funra wọn, wọn ni iwọn ẹẹdẹgbẹrin mita (700 square metres) ni wọn n
ta a pulọọti kan, ṣugbọn nigba ti wọn ti gbe e fun ileeṣẹ yi, wọn ti sọ ọ di iwọn ẹẹdẹgbẹta mita (500 square
metre).
Eyi to jẹ pabanbari ẹ ni bi wọn ṣe so pe eyi
to ku ti Oloye Ọbasanjoọ n lo ninu ilẹ naa ko to ida ogun (less than 20%) mọ
ninu ida ọgọrun (100%).
Ilẹ yi la gbọ pe o bẹrẹ lati itosi Alagbado
niluu Eko to si gba awọn agbegbe bii Itele ati Ipaja kọja, to fi de Ọta
nipinlẹ Ogun. Inu ilẹ yi naa ni Ọkunrin ọmọ bibi ilu Abẹokuta naa kọ ileewe Bell International ati
Fasiti Bell si.
Ohun tawọn kan n sọ ni pe ṣe Oloye Ọbasanjọ
ti mọ igba tabi akoko ti yoo ku ni, abi pe ṣe baba agba naa ti mọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ
lẹyin iku ẹ lo jẹ ko bẹrẹ igbeṣe naa lojiji, ṣugbọn ti ko tii sṣni to le dahun ẹ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment